Lucky ati Sheriff, ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ, ko sọwọ ọlọpaa n’lkorodu

Faith Adebọla, Eko

 

 

Ọwọ ọlọpaa ti ba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji kan, Sheriff ati Lucky Ndulume. Agbegbe Ikorodu ni wọn ti mu wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lẹyin ti wọn ti da wahala silẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ lawọn mejeeji. Wọn lawọn ẹlẹgbẹ wọn to wa ni Ikorodu lo ranṣẹ pe awọn mejeeji yii lati waa ba wọn gbẹsan bi iku ṣe pa ọkan lara wọn soju ija lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ n ba wọn ja.

Wọn ni lati ilu Oworonshoki ni Sheriff ti wa, nigba ti Lucky n gbe ni Igbo-Olomu, adugbo kan ti ko fi bẹẹ jinna si Ikorodu.

Iku ọkan lara wọn yii lo mu ki agbegbe Ikorodu kan gbinringbinrin lọjọ keji, ọjọ Aje, Mọnde, pẹlu bawọn eeyan ṣe n sọ pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun naa fẹẹ gbẹsan, eyi to tumọ si pe wọn fẹẹ tajẹ silẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni latigba ti iṣẹlẹ yii ti waye lawọn ọlọpaa ti n patiroolu kiri agbegbe naa, bẹẹ lawọn ọtẹlẹmuyẹ atawọn ẹṣọ fijilante Onyabọ n ba iṣẹ tiwọn lọ lẹgbẹ kan.

Oru ọjọ Tusidee lawọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun tun ko ipaya bawọn eeyan, ti wọn n le ara wọn kiri kitakita, tawọn janduku kan si n lo anfaani naa lati ja awọn ọlọja lole, ti wọn n fọ ṣọọbu wọn. Igba tilẹ ọjọ keji mọ lọwọ ba awọn meji yii, bo tilẹ jẹ pe awọn ẹlẹgbẹ wọn to ku ti sa lọ.

Lara awọn to sa lọ ti wọn n wa ni Fẹla, Aboki, Jẹlili, Small Sheriff atẹnikan ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘Loaded’.

Ibọn ilewọ meji ni wọn ri gba lọwọ awọn meji tọwọ ba yii, pẹlu ọta ibọn ti wọn o ti i yin, ada, aake ati egboogi oloro.

Bi Adejọbi ṣe wi, wọn ti taari awọn mejeeji sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, iṣẹ iwadii si ti n lọ lọwọ

Leave a Reply