Ma a ba Tinubu ṣiṣẹ pọ to ba ranṣẹ si mi – Bọde George

Monisọla Saka

Oloye Bọde George, ti i ṣe igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹka ti apa iha Guusu orilẹ-ede yii tẹlẹ, ti ko si figba kankan gba ti Tinubu, pẹlu bo ṣe figba kan lerileka lasiko ibo pe oun yoo fi Naijiria silẹ ti Tinubu ba di Aarẹ ni, ti sọ pe pẹlu idunnu ati ọyaya loun yoo fi ṣiṣẹ pẹlu Aarẹ tuntun, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ninu eto iṣejọba rẹ, to ba pe oun si i.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lo sọrọ yii fawọn oniroyin, lasiko ti wọn n ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun un lọọfiisi rẹ to wa lagbegbe Ikoyi, nipinlẹ Eko. O loun ko ni ija adaja kankan pẹlu Aarẹ, nitori bẹẹ lo ṣe jẹ pe oun ti ṣetan lati ba a ṣiṣẹ, koun si ran an lọwọ lawọn ibi to ba yẹ, fun ilọsiwaju ati idagbasoke ilu, niwọn igba to ba ti pe oun siru ọrọ bẹẹ.

O ni, “Ti Tinubu ba waa ba mi, to ni, ‘ẹ jọọ, ki lẹ ri si eleyii, ki ni ka a ṣe si tọhun, ẹ jẹ ka a ṣiṣẹ papọ nitori orilẹ-ede yii’, ki lo de ti mo maa sọ pe rara. Orilẹ-ede yii ṣaa lo tọ emi naa”.

“Awọn ileeṣẹ ologun ni wọn kọ mi, ti wọn se mi jinna. Ko ti i si apa ibi kan lorilẹ aye yii ti mi o ti i de ri. Ba a ṣe n lọ fun idanilẹkọọ si i la n lọ fun ere idaraya. Orilẹ-ede yii lo tọ wa. Nitori bẹẹ lawa naa ṣe gbọdọ sa ipa wa lati da oore ti yoo la ipa rere lori awọn ọdọ to n bọ lẹyin pada, lati le pa awọn naa lẹrin-in ayọ”.

Nigba to n gboriyin fun ẹgbẹ oṣelu APC lori alakalẹ eto wọn ti ko fi ofin kankan lelẹ lori bi wọn ṣe gbọdọ maa pin ipo, o ni,” Mi o ti i ri eto to daa to bẹẹ ri. Ṣe ẹ ranti pe nigba tawọn APC kọkọ de, wọn lawọn o nigbagbọ ninu ka maa gbe ipo yika ẹkun ilẹ Naijiria kaakiri, pe awọn o si nifẹẹ si iru nnkan radarada bẹẹ.

Amọ ki lohun ti wọn pada ṣe nigbẹyin, ẹ jẹ ka a beere lọwọ ara wa, ibi ti Buhari, Ọṣinbajo, olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, ati olori ileegbimọ aṣofin ti wa”.

O tẹsiwaju pe iru iṣoro yii gan-an lo ba ẹgbẹ PDP jẹ, to si sọ wọn dero ẹyin. Nitori apa ibi ti alaga apapọ ti wa, naa ni oludije funpo aarẹ ti wa.

“Nigba ta a si n gbiyanju lati sọ fun wọn pe wọn ti yọ apa Guusu Iwọ Oorun kuro ninu eto, niṣe ni wọn ni ka pada wa lẹyin idibo, ṣe bi a si ti ri atubọtan rẹ bayii”.

O ni ọrọ ikunsinu tabi ede-aiyede kọ lo wa nilẹ bayii, bi orilẹ-ede Naijiria yoo ṣe daa si i, ti yoo si goke agba ni koko, nitori bẹẹ loun yoo si ṣe gba lati ba Tinubu ṣiṣẹ pọ pẹlu ifẹ.

Leave a Reply