Maaluu meji ni Babatunde ji gbe tọwọ NSCDC fi tẹ ẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹsọ alaabo, ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti ẹni ọdun mejilelaadọta Rauf Babatunde, ni abule Dogo, Igbẹti, ipinlẹ Ọyọ, fẹsun pe o ji maaluu meji to jẹ ti arakunrin kan Abdul Rahman Umar to wa ni agbegbe naa gbe.

Ninu atẹjade kan agbẹnusọ ajọ ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, buwọ lu to tẹ akọroyin wa lọwọ lọjọ Ẹti, Furaidee, lo ti sọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni olori agbegbe kan ni Banni, lẹkun Ariwa ipinlẹ Kwara, Sheik Ahmed Mohammed Baba, mu ẹsun lọ si ọfiisi ajọ NSCDC to wa ni agbegbe naa pe wọn ti ji maaluu meji to jẹ ti Abdulrahman Umar to to ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) niye gbe lọ.

Afọlabi ni lasiko ti ajọ awọn atawọn fijilante bẹrẹ si i wa awọn afurasi ọhun ni wọn mu ẹni kan pẹlu maaluu meji to ji gbe ọhun, tawọn meji si sa lọ lara awọn ti wọn jọ ṣịṣẹ naa.

Babatunde ti wọn mu yii ti wa lakata ajọ NSCDC bayii fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

Alukoro yii ni awọn yoo ri i daju pe ọwọ tẹ awọn mejeeji to na papa bora.

Leave a Reply