Maaluu mejidinlaaadọrun-un ya wọ oko oloko n’Igangan, wọn ba agbado eeka mẹwaa jẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ẹkun nikan lo ku ti awọn agbẹ aladaa-nla niluu Igangan, nipinlẹ Ọyọ, ko le maa sun nigba ti maaluu mẹrindinlaaadọrun-un (88) ya wọnu oko wọn, ti wọn si jẹ oko agbado eeka mẹwaa kanlẹ loru ọjọ Abamẹta, Satide, mọju ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn agbẹ yii ni wọn da awọn oko agbado naa sẹgbẹẹ ara wọn. Nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ni wọn kuro ninu oko lọjọ Satide, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi pada denu oko laaarọ ọjọ keji ti i ṣe Sannde, maaluu ti fẹẹ fi gbogbo agbado oko wọn jẹ tan, iwọnba ti wọn ko si ri jẹ nibẹ, wọn ti ba gbogbo ẹ jẹ tan pata.

Bẹẹ, wọn ko ṣeeṣi ba ọkankan ninu awọn maaluu naa ninu oko yii, gbogbo wọn ti sa lọ patapata pẹlu olowo wọn.

Lẹyin ti awọn agbẹ to loko yii fẹjọ sun Serikin Fulani, iyẹn ọba awọn Fulani ilu Igangan, Alhaji Kadir Saliu, lọkunrin naa tọpase awọn maaluu naa lọ lati mu awọn olowo wọn. Lẹyin ọpọlọpọ irin, o ri awọn maaluu naa, ṣugbọn awọn olowo wọn ti na papa bora. N lo ba ko awọn maaluu naa lọ satimọle lagbala ẹ.

Lọjọ kẹta la gbọ pe awọn Fulani to ni awọn maalu naa yọju, ti ọba wọn si da awọn nnkan ọsin wọn pada fun wọn bo tilẹ jẹ pe wọn ko ṣe ojuṣe to yẹ fawọn agbẹ ti wọn ba oko wọn jẹ.

Awijare Alhaji Saliu ni pe ko ṣee ṣe fun oun lati ko maaluu mẹrindinlaaadọrun-un (88) sọdọ fun ọjọ pipẹ, nitori ẹ loun ṣe tete yọnda wọn fawọn olowo wọn pe ki wọn lọọ ṣe ojuṣe to ba yẹ fawọn agbẹ ti wọn fẹran jẹ oko wọn.

Ẹgbẹ awọn agbẹ aladaa-nla niluu Igangan ti wọn pe ara wọn ni Igangan Agro Park Investors Association ti waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati wa nnkan ṣe si bi awọn Fulani ṣe n da gbese sawọn agbẹ lọrun lagbegbe naa pẹlu bi wọn ṣe maa n fẹran jẹ oko wọn nigba gbogbo.

Alaga ẹgbẹ ọhun, Ọgbẹni Olufẹmi Abioye, sọ pe ọpọ igba ti awọn Fulani ba ko maaluu lọọ jẹ oko oloko yii ni wọn ki i fun oloko ni nnkan gbà-ma-bíínú kankan, to jẹ pe awọn agbẹ ni wọn maa dàyà kọ gbese ti awọn ọlọsin maaluu naa ba da si wọn lọrun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nnkan to maa n dun eeyan ju nibẹ ni pe ti awọn Fulani yii ba fi maaluu ba eeyan loko jẹ nigba mi-in, ti oluwa ẹ ba sọrọ, wọn le tun doju ija kọ onitọhun. Bẹ ẹ ba tun fọlọpaa mu wọn naa, awọn Fulani wọnyi ko ni i ṣe ẹtọ to ba yẹ ki wọn ṣe foloko.

“Iyẹn lo ṣe jẹ pe laarin ọdun to kọja yii nikan, iṣiro owo nnkan oko wa ti awọn maalu bajẹ ta a ṣe jẹ miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (N2.4m).

“Nigba ta a fọrọ yii lọ Seriki Fulani gan-an, o ni iwọnba loun le da si ọrọ awọn Fulani onimaaluu mọ nitori awọn kan wa ninu wọn to jẹ pe ere bi wọn yoo ṣe doju ija kọ eeyan, ti wọn yoo si ṣe oluwa ẹ leṣe ni wọn maa n sa.”

Leave a Reply