Maaluu ni Faruq ati Jobo ji gbe tọwọ fi tẹ wọn ni Kwara  

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹsọ alaabo (NSCDC) ẹka ti ipinlẹ Kwara ti mu Issa Faruq ati Jobo Gorokunaa, labule Biogberu, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, fun ẹsun pe wọn ji maaluu mẹfa ati ọkada gbe.

ALAROYE gbọ pe Alhaji Megiwa to jẹ Fulani, to n gbe ni abule Biogberu, lo mu ẹsun lọ sọdọ ajọ (NSCDC) pe awọn afurasi mejeeji ọhun ji maaluu oun mẹfa, akọ marun-un, abo kan, gbe lọ, ati pe gbogbo igbiyanju awọn fijilante lati wa  awọn maaluu naa ri lo ja si pabo.

Agbẹnusọ (NSCDC) ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, sọ pe, nigba ti ọwọ awọn ba afurasi mejeeji naa tan ni wọn n ka boro boro pe loootọ lawọn ji maaluu rẹ, ti awọn si ti ta a si abule Gwanara ati Paraku, ni ilẹ Olominira Benin. Bakan naa ni awọn tun ji ọkada kan gbe lẹyin ti awọn ji maaluu tan, ti awọn si yinbọn ibilẹ to wa lọwọ awọn soke lati fi sẹru ba awọn eeyan.

Lakooko ti iwadii n lọ lọwọ ni Alhaji Megiwa pada si ọdọ awọn ẹsọ alaabo, ti o si sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun bi oun ṣe ba maaluu marun-un, ninu mẹfa ti wọn jigbe ninu ọgba oun, ti oun ko si mọ bi wọn ṣe debẹ pada. Ajọ naa bere iye ti maaluu ẹyọ kan jẹ, o ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (#100,000) ni, ni wọn ba ni ki awọn afurasi mejeeji san owo maaluu ẹyọ kan to ku fun Fulani yii ko maa ba tiẹ lọ.

Bakan naa, wọn tun ni ki awọn afurasi ọhun gbe ọkada fun ẹni ti o ni i, ki wọn si fun un ni ẹgbẹrun mejidinlaaadọta naira (#48,000) owo wahala to ṣe nigba to n wa ọkada rẹ, ni wọn ba gba oniduuro awọn mejeeji, wọn si ni ki wọn maa rele.

Leave a Reply