Magaji Nda: Ọtẹ ati jamba ni Alimi fi gba Ilọrin, ki i ṣe Jihaadi

Ẹ ma binu si mi pe mo ya bara kuro lori itan ti a n sọ bọ tẹlẹ. Ẹyin ti ẹ n daamu mi pe ṣe mo ri ohun ti wọn n ṣe fun Bọla, tabi pe ki la fẹẹ ṣe bayii. Mo ti sọ fun yin pe ko si kinni kan ti a fẹẹ ṣe si ọrọ ti Bọla, nitori Bọla ko ṣe kinni kan fun Yoruba, oun n fi orukọ Yoruba jẹun oṣelu ni. Iru awọn eeyan ti awọn Fulani n fẹ niyẹn, ẹni ti yoo kọyin si iya ati baba rẹ, ti yoo kọyin si awọn eeyan rẹ, ti yoo maa ba wọn ṣe, ti wọn yoo maa ri i lo lati fi rẹ awọn eeyan tirẹ jẹ, nigba ti wọn ba lo o tan, wọn yoo sọ ọ ju silẹ bii eepo ọsan, bi ko ba si ṣọra, wọn yoo pa a danu ki wọn le jẹ ko raaye ṣe tiwọn. Bi tọhun ba ku tan, awọn eeyan naa yoo dori itan kodo, wọn yoo ni baba awọn lo nilẹ, awọn lawọn ni gbogbo agbara. Iru ohun ti wọn ṣe fun Ladoke Akintọla niyẹn, nigba ti awọn Sardauna n lo o lati fa Yoruba sẹyin, ti wọn lo o lati sọ Awolọwọ sẹwọn, ki wọn le yi esi sẹnsọ ọjọ naa pada, ki wọn le ni Hausa-Fulani pọ ju Yoruba lọ.

Ṣebi ohun ti wọn ṣe fun Afọnja naa ree, loju wa lai ti i ku yii naa, ni Magaji Nda Ilọrin ti fẹẹ yi itan pada yii, to ni Jihaadi ni Alimi fi gba Ilọrin. Iru awọn yii ni wọn ṣe e tijọba Naijiria fi lawọn o ni i jẹ ki wọn kọ awọn ọmọ ni itan nileewe wọn mọ, ti wọn si fi ọpọ ọdun fagi le e.  Mo ṣi n bọ lori ọrọ Mọgaji Nda yii. Ṣugbọn ni ti Bọla, ẹ ko ti i ri nnkan kan, ẹ oo ṣi ri mẹwaa, oju wa naa ni yoo ṣe. Awọn ti wọn gbe e soke yii naa ni wọn yoo jan an mọlẹ, nitori wọn ti lo o tan, wọn si ti ri i pe ko wulo fawọn mọ. Wọn yoo fi i silẹ ti yoo maa ṣa ohun to ba ri jẹ lẹgbẹẹ wọn ni. Ko ni agbara ẹyọ kan bayii ninu ijọba apapọ yii mọ, ṣugbọn ko ni i sọ fun-un-yan, ki awọn ti wọn n tẹle e le tubọ maa bu ọla fun un, ki wọn maa ro pe alagbara nla ni nile ijọba. Bẹẹ, Eko nikan ni agbara ẹ wa, lọjo tawọn araabi ba si gba Eko lọwọ ẹ, lọjọ naa ni gbogbo kurakuta pin.

Awọn eeyan beere pe kin ni yoo ṣẹlẹ si i, kin ni yoo ṣẹlẹ si Bọla, ṣe wọn o ni i pa a bayii, ṣe wọn o ni i sọ ọ sẹwọn ti ko ba fẹẹ gbe agbara silẹ fun wọn. Ẹrin ni mo maa n rin, nitori o pẹ ti mo ti n sọ ọ pe Bọla ko ni i jẹ ki wọn ṣe kinni kan foun. Ohun ti awọn ṣe n ro pe aburu kan le ṣẹlẹ si i ni pe wọn ṣe bi eeyan bii Awolọwọ ni. Awọn eeyan naa ko mọ Bọla rara. Bi ẹ ko ba mọ, ọga awọn ojo ni Bọla. Ọlẹ ati ojo buruku kan bayii ni, ki i ṣe ẹni ti yoo ṣaaju, ti yoo ni ki ṣọja tabi Fulani yinbọn ti wọn ba fẹẹ yinbọn wọn, nigba ti ọrọ yoo ba fi da bẹẹ, yoo ti waa niluu oyinbo tipẹ, ibẹ ni yoo ti maa ranṣẹ wale ti yoo ni awọn n ja fun awọn mẹkunnu ni. Bi ọrọ ba di ọrọ oṣelu Naijiria, ọlẹ ni Bọla; ọlẹ ti ẹ ri yẹn si mọ eewọ ija, bi wọn ni yoo ba iya rẹ, yoo ni ko ni i ba iya ẹnikankan awọn; bi wọn gba a leti ọtun, yoo si yi tosi si i fun wọn. Tabi ẹni ti ẹ bu iya rẹ ti ko sọrọ, ti ẹ gba leti ti ko ba yin ja, ẹ o wa pa a bi.

Ẹ wo ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja yii. Wọn pe ọ ni aṣaaju pata fun ẹgbẹ yin, wọn fẹẹ ṣepade ẹgbẹ naa, wọn ko pe ọ, ko sẹni to wi fun ọ. Wọn de ipade naa, wọn yọ gbogbo awọn ti wọn jẹ tirẹ nibẹ danu, sibẹ ko sẹni to pe ọ to sọ idi ti wọn ṣe ṣe bẹẹ fun ọ. Gbogbo eeyan wa n gbe e kiri pe ki lo n ṣẹlẹ si ọga awọn, iwọ ọlọrọ waa jade, o ni ko si eyi to kan wọn, ọrẹ ni iwọ ati Buhari, pe ko si ija laarin awọn rara, olori ẹgbẹ awọn ni, pẹlu awọn ọrọ isọkusọ mi-in. Nigba ti alara ni ara ko ro oun, ki waa ni temi lati maa sọ fun un pe o ku aisun, o ku aiwo si. Gbogbo ilẹ Yoruba, titi de ilẹ Hausa, ni wọn ti n pariwo pe Bọla yoo ṣe aarẹ ni 2023, ṣugbọn ojo ati ọlẹ ko jẹ ki oun funra ẹ le sọrọ lori ohun to n nawo le, to n na gbogbo agbara ẹ le lori, o ni oun ko ti i ṣetan lati du ipo ni 2023, iṣẹ Buhari lawọn n ṣe lọwọ.

Ohun ti mo ti sọ fawọn eeyan lọjọ to ti pẹ niyẹn, pe to ba ku oni ku ọla ti Bọla yoo du ipo aarẹ, ti awọn Hausa-Fulani to n tẹle wọnyi ba halẹ mọ ọn, yoo jawọ nibẹ kia, yoo si sọ awọn ti wọn n tẹle e yii si kolombo, yoo ni oun ko ran wọn niṣẹ, oun kọ loun bẹ wọn ni iṣẹ ti wọn n ṣe. Ko si ohun mej ti yoo mu un ṣe bẹẹ ju pe oun naa mọ awọn ohun ti oun ti ṣe pamọ ti ko dara, o mọ awọn iwa ti oun ti hu ti araalu ko gbọdọ gbọ, o mọ awọn ohun ti oun n bo mọlẹ ti ko gbọdọ lu sita. Ṣe ti ibi ti wọn ti bi i ni; ṣe ti ẹni to bi i ni; ṣe ti ileewe to lọ ni; ṣe ti oun to ṣẹlẹ si i niluu oyinbo ni; ṣe ti bo ṣe di olowo aye bayii ni; ati awọn nnkan mi-in ti isalẹ wọn lẹgbin gan-an. Awọn yii ni Bọla n bo mọlẹ. Ṣugbọn oun nikan kọ lo mọbi to bo o mọlẹ si, awọn Hausa-Fulani yii mọbẹ, o si mọ pe ti oun ba ṣẹ wọn, wọn yoo hu u jade.

Eyi lo ṣe jẹ ti wọn ba sọ pe ‘hoo’, Bọla naa yoo sọ pe ‘hoo’ ni. Bi wọn ba ni ‘o kun’, o kun naa ni; bi wọn ba si ni ‘o fa’, o fa naa ni. Tabi ẹni meloo lo le ki oriki Buhari to bi Bọla ti ki oriki ọmọkunrin Fulani naa lọsẹ to kọja yii. Lẹyin ti wọn ti foju ẹ gbolẹ, o mu oriki awọn ti wọn ṣe e bọnu. Ta lo n ṣe bẹẹ bi ko jẹ ojo ati ọlẹ! Bi Bọla ti ri niyẹn. Ṣugbọn ẹni ti wọn na ni kumọ mẹfa loju gbogbo aye, to de kọrọ to ni ọkankan ko ba oun nibẹ, ṣebi oun ni ara rẹ yoo ro. Ẹ jẹ ki Bọla maa tan ara rẹ ko ro pe oun n tan ẹni kan, ọrọ ni yoo sọ ara rẹ bo ba ya.    

Ni ti ọrọ Salihu Muhammed, Magaji Nda ilu Ilọrin, mo fẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba Ilọrin pata gbọ, ki gbogbo ẹya Fulani Ilọrin naa si gbọ, arẹnijẹ lasan ni iru awọn eeyan bayii, awọni ni wọn n da ogun silẹ nibi ti ko ti si ogun. Nigba ti eeyan ba fẹẹ jẹ ogun ologun, ogun ti ko tọ si i, itan buruku ni yoo maa ti ẹnu rẹ jade. Mo ti sọ itan Ilọrin nibi yii laimọye igba, koko to si wa nibẹ naa ni pe ilẹ Yoruba ni ilu Ilọrin, ilẹ Yoruba ni, ki i ṣe ilẹ Fulani, awọn ọmọ Yoruba lo si pọ ju nibẹ titi di bi a ṣe n sọ yii. Ẹsẹ ni Alimi fi rin wa si ilu Ilọrin, ki i ṣe ori lo fi rin debẹ. Amọ ki i ṣe Jihaadi lo gbe e wa bi Magaji Nda ṣe wi yii, o ba iṣẹ aafaa wa ni, atijẹ-atimu lo ba wa sibẹ, iṣẹ aje rẹ lo n ṣe kaakiri. Afọnja ti i ṣe aarẹ-ọna-kankanfo lo n ba Alaafin to fi i joye ja, nitori ki apa awọn ọmọ ogun Yoruba bii tirẹ ma si ṣe ka a lo ṣe ranṣẹ pe Alimi: akọkọ, pe ko ṣe iṣẹ aafaa foun, ẹẹkeji, ko ba oun ko awọn Hausa ati Fulani to n ṣe iṣẹ ẹru ati alagbaro jọ, ki oun le lo wọn bii ọmọ ogun.

Aṣiṣe ti Afọnja ṣe niyi, lati wa iranlọwọ lọ sita. Igba ti wọn jagun tan, ti wọn ṣẹgun, ti wọn le awọn jagunjagun ilẹ Yoruba yii lọ ni awọn ọmo Hausa-Fulani ti Alimi ko wa lati ran Afọnja lọwọ bẹrẹ iwa palapala, ti Alimi si n kin wọn lẹyin. Afonja kilọ fun wọn, wọn ko gbọ, titi ti ọrọ naa fi waa dogun, ti Alimi si ta jamba fun Afọnja, to fi ọtẹ buruku ba ilu rẹ lọ. Ṣe ọmọ Ṣokoto ni Alimi ni. Abi Jihaadi wo lo ti ṣe nibi kan ri, nibo lo ti n gbe Jihaadi tiẹ bọ ko too de ilu Ilọrin, abi nigba to ji ni aarọ nile rẹ, Ilọrin lo ni oun n lọ, ti oun n lọọ ṣe Jihaadi. Ọmọ ogun meloo ni Alimi ko de Ilọrin. Alimi ko ko ọmọ ogun de Ilọrin, nitori ki i ṣe onijihaadi, iṣẹ aafaa lo waa ṣe, o loun yoo ran Afọnja lọwọ lati ṣegun awọn ọta rẹ ni. Ṣugbọn iranlọwọ to ṣe fun un, jamba lo fi ta fun un. Awọn eeyan bii Alaaji Nda yoo mọ itan yii, ṣugbọn nitori ati mu ori Ilọrin mabẹ, ki wọn maa jẹ ilu naa ni wọn ko ṣe ni i sọ tootọ.

Ewe ti pẹ lara ọṣẹ, o ti dọṣẹ, Fulani Ilọrin ti di Yoruba, Yoruba si ti di Fulani Ilọrin. Mo sọ fun yin nibi yii pe iya to bi awọn ọba akọkọ Ilọrin, ọmọ Yoruba ni i ṣe. Eyi ni pe ko si Fulani taara n’Ilọrin, Yoruba ni gbogbo wa. Ṣugbọn awọn kan wa ti wọn jẹ onijẹkujẹ, awọn arẹnijẹ, awọn alapamaṣiṣẹ to jẹ owo ilu ni wọn n jẹ. Awọn yii ni wọn n fi tipatipa pe Ilọrin ni ilu Fulani, nitori ki wọn le maa rẹ awọn eeyan jẹ ni. Ẹni yoowu ti ẹ ba ri to ba n ṣe bẹẹ, ẹ jinna si i o, awọn ọta ilu Ilọrin lẹ ri yẹn.

4 thoughts on “Magaji Nda: Ọtẹ ati jamba ni Alimi fi gba Ilọrin, ki i ṣe Jihaadi

  1. Huuuuun mo gbadun itan yii pupo, afi bi enipe e ri inu mi, oro yii lemi ati awon Ore mi jiyan si lanaa, mo so fun mo ni eru nba Tinubu idi niyii ti ko ti fi so pe ohun yoo dupo aare ni 2023 tori o mo pe agbara awon Hausa ju ti ohun lo, awa Yoruba si re e ohun taa o je nikan lamo. Kolorun saanu gbogbo wa

  2. Isokuso pata gba ni olukotan Yi so nipa itan ilorin, nitori olukotan komu eri to pe ye wa Lati tako Oro magaji nda. Osi daju wipe olukotan koma itan ilorin rara. awawi, inuni bini ati ona ati fi gege ta oja re lo mun ni okukundun.

  3. O n ti momo nipa saliu Mohammed oko iya to won n pe ni mogaji Nda ni pe koni enu oro lati ma so Itan Ilorin nitori baba baba e je olori apoko fesin je fun emir ilorin loje,

Leave a Reply