Makinde ṣabẹwo si Olunlọyọ, o fun un ni mọto olowo nla

Olawale Ajao, Ibadan

Titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn eeyan ṣi n ki gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Dokita Ọmọlolu Olunlọyo, ku oriire ti ẹbun mọto nla ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fi ta a lọrẹ ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii.

Bẹẹ lawọn eeyan naa si n dupẹ lọwọ Makinde naa fun bo ṣe ronu ohun rere kan gomina atijọ yii.

Lẹyin ti Makinde kuro nibi aṣekagba inawo oku Olubadan tilẹ Ibadan to waja laipẹ yii, Ọba Saliu Adetunji, lo gba ile Olunlọyọ to wa ni Mọlete, niluu Ibadan lọ, oun pẹlu awọn lọgaa lọgaa lẹnu iṣẹ ọba ni wọn jọ kọwọọrin lọ sibẹ.

Bi wọn ṣe debẹ ni Makinde wọle ipade bonkẹlẹ pẹlu Olunlọyọ. Lẹyin ipade naa lo bọ sita, lo ba nawọ si mọto Lexus jeep alawọ ewe kan, lo ba ni ‘Ọlọla ju lọ, ẹ jẹ ki n fun yin ni ẹbun yii.’’

Ṣaaju akoko yii lo ti ni ki wọn ṣe atunṣe si ile ti gomina naa n gbe, ti wọn tun gbogbo rẹ ṣe, ti wọn si kun un lọda, to ti dun un wo daadaa.

Lasiko to ṣabẹwo si ile naa ni Olunlọyọ ki i, o yin in fun iṣẹ rere to n ṣe, o si gbadura fun un pe yoo maa saṣeyọri siwaju si i.

O fi idunnu rẹ han si ipa ti Makinde ko ati bo ṣe ṣe ẹyẹ ikẹyin to daa fun Olubadan ilẹ Ibadan ati Ṣọun Ogbomọsọ. O gboṣuba kare fun gomina naa, o ni iṣe daadaa lo n ṣe nipinlẹ Ọyọ.

Leave a Reply