Faith Adebọla
Ṣinkin ni inu awọn araalu, awọn akẹkọọ atawọn alakooso ileewe olukọni (College of Education), to wa niluu Lanlatẹ, nipinlẹ Ọyọ, n dun, nigba ti gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ṣabẹwo siluu naa, to si fi miliọnu lọna ọgọrun-un (N100m) Naira ta ileewe naa lọrẹ.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanla, oṣu keji yii, ni Makinde ati ikọ rẹ ṣabẹwo ọhun, o lo wa lara awọn irinajo tijọba oun ṣeto lati foju ara oun ri bi nnkan ṣe ri lẹka eto ẹkọ, paapaa lagbegbe Ibarapa, Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ.
Bi gomina ti n wọ ilu naa lawọn araalu ti tu jade lati ki i kaabọ, bẹẹ lawọn akẹkọọ, awọn olukọ, ati alaga ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ibarapa pẹlu awọn ọmọ igbimọ alakooso rẹ waa yẹ Makinde si.
Ajagun-fẹyinti Bisi Ọjẹbọla to jẹ alaga igbimọ alakooso kọlẹẹji naa ba gomina sọrọ, o sọ nipa ipenija to n koju ileewe naa, titi kan awọn ipese nnkan eelo ikẹkọọ atawọn yara ikẹkọọ to ti bajẹ, to si n fẹ atunṣe. O lo ṣe pataki kijọba ran awọn lọwọ, tori ileewe naa ṣanfaani fawọn ọdọ agbegbe naa, ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ.
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ nileewe naa, Quadri Alao, tun ṣalaye fun gomina nipa awọn ipenija tawọn akẹkọọ n koju, o si gboṣuba fun iṣakoso Ṣeyi Makinde pe eto aabo ti sunwọn si i lasiko yii ju tatẹyinwa lọ.
Oriṣiiriṣii akọle lawọn akẹkọọ naa gbe dani, lati fi imọriri wọn han si abẹwo gomina ọhun, ati lati sọ ẹdun ọkan wọn pẹlu.
Makinde dẹrin-in pẹẹkẹ awọn eeyan ọhun, nigba to sọ fun wọn pe miliọnu ọgọrun-un toun ṣeleri naa ki i ṣe ọrọ lọ-kabọ rara, o ni loju-ẹsẹ toun n sọrọ naa ni wọn yoo gba idaji owo ọhun, ti wọn wọn yoo si gba aadọta miliọnu naira to ku nibẹrẹ oṣu kẹfa, ọdun yii.
O rọ wọn pe ki wọn ma ṣe owo naa baṣubaṣu o, ki wọn na an sori mimu itẹsiwaju ba ileewe naa ni.
O si tun sọ fawọn araalu pe awọn ipenija to n koju wọn ti wọn ti fi to oun leti yoo yanju laipẹ, o ni ki wọn lọọ fọkan balẹ.