Makinde ṣeto aabo fun awọn oluwọde l’Ọyọọ, o ti gbogbo ileewe pa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe awọn ọmọọta ati awọn ọmọ ganfe ti ja eto iwọde SARS to n lọ lọwọ gba pẹlu bi wọn ṣe n fa wahala loriṣiiriṣii, ti wọn si n di awọn eeyan lọwọ lati ṣiṣẹ wọn.

Latari eyi, gomina ti paṣe pe ki awọn ọlọpaa adigboluja ti wọn n pe ni ‘Operation Burst’ bọ sita kaakiri ipinlẹ Ọyọ, ki wọn lọ si awọn ibi ti awọn to n ṣe iwọde ti n ṣe e lati daabo bo wọn lọwọ awọn ọmọ ganfe ti wọn le fẹẹ da eto naa ru.

Lasiko ti gomina n ba awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ sọrọ lori bi nnkan ṣe n lọ si lori ọrọ iwọde naa lo sọ eleyii. Makinde ni latigba ti iwọde naa ti bẹrẹ, ko fi bẹẹ si wahala kankan, ṣugbọn lẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn tọọgi ja iwọde naa gba, ti wọn si n di awọn eeyan lọwọ lati lọ sibi iṣẹ oojọ wọn, eyi to ni ko bojumu to.

Eti lo fi ni ijọba yoo ko awọn ọlọpaa adigboluja jade lati daabo bo awọn to n ṣe iwọde naa, ki aabo to daju le wa fun wọn, ki awọn ọmọọta ma si le da a ru.

O waa rọ awọn ọlọpaa lati fi iwa ọmọluabi ṣiṣẹ ti wọn gbe fun wọn yii. Bẹẹ lo pasẹ pe ki gbogbo ileewe nipinlẹ Ọyọ di titi pa lasiko yii. O ni awọn yoo ṣe agbeyẹwo bi gbogbo nnkan ba tun ṣe ri ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, lati mọ igbesẹ to ba kan.

Leave a Reply