Makinde bẹrẹ iwadii lori ọga ileewe tawọn wolewole lu lalubami n’Ibadan

 Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti wọn lu oludasilẹ ileewe aladaani kan, Ọlayemi Sylva, lalubami nigboro Ibadan, ti wọn si tun fọlọpaa gbe e, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti bẹrẹ iwadii lori ija naa pẹlu ipinnu lati fiya jẹ ẹni to ba jẹbi ninu wọn.

Ninu àkásílẹ̀ ohùn kan ti Abilekọ Ọlayemi fi ranṣẹ sawọn eeyan, eyi to ti gba ori ẹrọ ayelujara kan bayii, lo ti ṣalaye bi awọn oṣiṣẹ eleto imọtoto ayika ipinlẹ Ọyọ ṣe fiya jẹ ẹ to.

Gẹgẹ bii awijare oludasilẹ ileewe naa, o ni ọkan ninu awọn akẹkọọ oun lawọn oṣiṣẹ eleto ilera mu fun ẹsun pe o dalẹ̀ soju títì, oun si lọ si olu ileeṣẹ awọn ajọ naa lati gba ọmọ yii silẹ, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ijọba naa sọ ọ dija mọ oun lọwọ, wọn ni oun n di awọn lọwọ lẹnu iṣẹ.

O ni nigba ti oun sọ ọrọ naa di ariwo mọ wọn lọwọ ni wọn fi ọlọpaa mu oun lẹyin ti wọn lu oun bii ejo aijẹ tan.

Ohun ti obinrin yii fi ranṣẹ, to si tan kaakiri ori ẹrọ ayelujara ni Gomina Makinde gbọ to fi gbe igbimọ oluwadii dide lati tọpinpin ọrọ naa, ki wọn si fi oju aṣebi lori iṣẹlẹ yii han ijọba ipinlẹ Ọyọ fun iya jẹ.

 

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Taiwo Adisa ti i ṣe akọwe iroyin Gomina Makinde gbe jade lorukọ ọga rẹ lo ti sọ pe ijọba oun ko ni i faaye gba oṣiṣẹ ijọba tabi ajọ to n ṣoju ijọba kan laaye lati fiya jẹ araalu kankan lọna aitọ, bakan naa lo ni awọn ko ni i gba fun ẹnikẹni lati maa huwa to lodi sofin.”

 

Leave a Reply