Makinde bẹrẹ itọju awọn Fulani to fara pa n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Nitori bi awọn amookunṣika kan ṣe yinbọn pa awọn maaluu awọn Fulani kan nibi ti wọn ti n da awọn nnkan ọsin naa jẹ kaakiri jẹẹjẹ wọn, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti bẹrẹ itọju fawọn Fulani to fara pa nibi iṣẹlẹ naa.

Lọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, to kọja, láwọn ika ẹda ọhún ti ẹnikẹni kò tí ì mọ lọọ ka awọn Fulani kan mọ ibi ti wọn ti n da ẹran wọn jẹ kiri inu igbo laduugbo Aláfàrà, nitosi Ológúnẹrú, n’Ibadan, ti wọn sì yinbọn pa pupọ ninu awọn maaluu wọn.

Lẹsẹkẹsẹ ti iroyin yii ti to Gomina Makinde leti lo ti ṣèlérí fawọn Fulani naa pe gbogbo owo maaluu wọn tó kú ọhun loun yóò san fún wọn.

Ninu atẹjade to fi ṣọwọ́ sawọn oniroyin nirọlẹ ọjọ keji ti í ṣe ọjọ Aiku, Sannde, to kọja, ni Akọwe iroyin fun Gomina Makinde, Ọgbẹni Taiwo Adisa, ti fìdí ẹ mulẹ pe gomina naa ti pàṣẹ fún ileeṣẹ eto ilera ijọba ipinlẹ naa lati mojuto bi wọn ṣe maa tọju awọn Fulani to fara pa lasiko ikọlu naa nileewosan n’Ibadan.

Ṣaaju nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, labẹ akoso CP Ngozi Onadeko, ti sọ pe ikọlu ọhun ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu ija Yoruba ati Fulani rara.

CP Ọnadeko ni ba a ṣe n sọrọ yii, alaafia ti jọba lÁláfàrà, ohun gbogbo si ti n lọ ni mẹlọmẹlọ lagbegbe naa nitori loju-ẹsẹ ti wọn ti fi iroyin naa to oun leti loun ti ran ọpọlọpọ ọlọpaa lọ lati lọọ pese aabo to peye sibẹ.

O waa ṣeleri láti mu awọn ọdaran naa laipẹ níbikíbi ti wọn ba sa pamọ si.

Leave a Reply