Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori aikunju oṣunwọn wọn, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde, ti da ajọ to n mojuto eto imọtoto ayika ipinlẹ Ọyọ ka, o ni wọn ko mọṣẹ wọn niṣẹ.
Ajọ eleto imọtoto yii ni wọn n pe ni Oyo State Waste Management Authority, OYOWMA lede oyinbo.
Nileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan ipinlẹ Ọyọ (BCOS) ni Gomina Makinde ti fidi iroyin yii mulẹ nigba ti ileeṣẹ ọhun gba a lalejo lori eto wọn kan l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.
O ni igbesẹ oun yii ko ṣẹyin bi ajọ naa ṣe kuna lati maa palẹ awọn ẹgbin ti awọn araalu n da jọ soju titi mọ gẹgẹ bo ṣe yẹ ki wọn maa ṣe e.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, owo tijọba ipinlẹ Ọyọ n na loṣooṣu lori pe a n kólẹ̀ danu lasan ko din ni miliọnu mẹtadinlogoji Naira (N37m).
Makinde ni bi ki i baa ṣe pe ijọba oun ki i ṣe oninaa-apa ni, mẹrindinlaaadọta (N46 m) Naira ti ajọ OYOWMA beere fun lati maa fi palẹ idọti mọ loṣooṣu.
“Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ba a ṣe n nawo to lati ri i pe igboro ilu Ibadan ati gbogbo ipinlẹ Ọyọ wa ni imọtoto, niṣe ni gbogbo oju titi tun kun fun idọti, ti awọn adugbo mi-in ko yatọ si aakitan.”
Lati ri i pe ẹgbin ko ba ogo ipinlẹ naa jẹ nitori idaduro igbimọ alamoojuto eto naa, Makinde sọ pe igbimọ alabẹ ṣekele kan ti oun ṣẹṣẹ gbe kalẹ ni yoo maa mojuto eto imọtoto ayika jake-jado ipinlẹ naa bayii, oun si gbagbọ pe igbimọ yii yoo ṣatunṣe si gbogbo aiṣedeede ajọ OYWMA.
O waa rọ gbogbo awọn ti ajọ naa ti fi aiṣedeede wọn pa lara laarin oṣu kan sẹyin lati fiye denu. Bẹẹ lo fi da wọn loju pe wọn yoo ri ayipada rere pẹlu iṣọwọṣiṣẹ igbimọ ti oun ṣẹṣẹ gbe kalẹ yii.
EFCC ya wọ ile igbafẹ kan n’Ibadan, ọmọ ‘Yahoo’ mẹwaa ni wọn ri mu