Makinde darapọ mọ ẹgbẹ APC l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ


Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ila-Oorun ati Iwọ-Oorun Ondo nile-igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọnarebu Abiọla Makinde, naa ti kẹru rẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) to wa tẹlẹ, o si ti lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).
Aṣofin ọmọ bibi ilu Ondo ọhun fi eyi lede ninu lẹta kan to kọ si Olori ile, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, lasiko ijokoo awọn aṣoju-ṣofin to waye lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Makinde fidi rẹ mulẹ ninu lẹta to kọ naa pe ija ajakuakata to wa ninu ẹgbẹ ADC, eyi ti wọn ko ti i ri yanju lo ṣokunfa igbesẹ ti oun gbe lati lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ọkan ninu awọn ọmọlẹyin gomina Ipinlẹ Ondo ana, Dokita Olusẹgun Mimiko, ni Ọnarebu Makinde, ẹni tawọn alatilẹyin rẹ tun n pe ni Osaparapara.
O ti figba kan ṣe alaga ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo kí aarin oun ati ọga rẹ too daru nigba naa.
Ọnarebu Joseph Akinlaja to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party bayii ni aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ mejeeji ọhun ki awọn eeyan too fi ibo wọn le e danu lasiko eto idibo gbogbogboo to waye lọdun 2019, ti wọn si fi ibo wọn gbe Makinde wọle.
Lasiko eto idibo gomina ipinlẹ Ondo to waye ninu osu kẹwaa, ọdun to kọja, lawọn eeyan ti n fura pe o ṣee ki ọkunrin tí wọn n pe ni Osaprapra naa darapọ mọ ẹgbẹ APC pẹlu bi oun atawọn alatilẹyin rẹ ṣe ṣatilẹyin fun Gomina Akeredolu, to si kẹyin si Agboọla Ajayi to jẹ oludije ti ọga rẹ atijọ fa kalẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party.

Leave a Reply