Makinde fun Ṣọun lọgọrun-un kan miliọnu lati tun aafin ẹ tawọn janduku bajẹ ṣe

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinni Ṣeyi Makinde, ti fun Ṣọun Ogbomọṣọ, Ọba Jimọh Ọladunni Oyewumi, ni miliọnu lọna ọgọrun-un naira (100m) lati tun aafin ẹ ti awọn janduku bajẹ laipẹ yii ṣe.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni gomina ṣabẹwo si kabiyesi, to si fi owo naa ta a lọrẹ. Ṣaaju lawọn eeyan kan to n fẹhonu han lori iku Jimọh Isiaq, ẹni to ku iku ojiji latari iwọde awọn to n fẹhonu han nitori FSARS, ti ya bo aafin Ṣọun, ti wọn ba ọpọlọpọ nnkan jẹ nibẹ, koda, ori lo ko kabiyesi ati minisita ana kan yọ lọwọ wọn.

Bakan naa ni Makinde de ile awọn obi Jimọh ti ibọn ba lasiko iwọde ifopin si SARS ọhun, o ba baba rẹ kẹdun nile wọn to wa lagbegbe Alasa, l’Ogbomọṣọ, o si fun wọn lowo pẹlu.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: