Ọlawale Ajao, Ibadan
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ro ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa lagbara lati le da duro laaye ara wọn.
Pẹlu igbesẹ yii, awọn aṣofin ipinlẹ yii ko ni lati maa woju ẹka alaṣẹ ijọba mọ ki wọn too le rowo gbọ bukaata yoowu ti wọn ba fẹẹ gbọ.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni gomina buwọ lu ofin naa ni gbongan igbalejo rẹ atawọn igbimọ alaṣẹ ijoba ipinlẹ naa to wa ninu ọgba Sẹkiteriati, l’Agodi, n’Ibadan.
Gomina pẹlu awọn aṣofin, eyi ti Ọnaarebu Debọ Ogundoyin ti i ṣe alakooso ileegbimọ naa ko sodi ni wọn peju pesẹ sibi eto ọhun.
Bakan naa lawọn aṣofin lo oore-ọfẹ apejọ naa lati buwọ lu abadofin eto iṣuna ọdun 2022.
Nigba to n gboriyin fun wọn lori bi wọn ṣe tete buwọ lu abadofin eto iṣuna ọhun, Gomina Makinde woye pe ominira ileegbimọ aṣofin ti oun naa fọwọ si yii yoo mu ki iṣẹ idagbasoke ilu ya kiakia fun ijọba.
Lara awọn to tun wa nibi eto ọhun ni olori awọn oṣiṣẹ gomina, awọn kọmiṣanna ninu iṣejọba yii ati bẹẹ bẹẹ lọ.