Makinde fun mọlẹbi awọn ti aṣọbode yinbọn pa niluu Isẹyin miliọnu kọọkan naira

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣeleri lati fun mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ninu ija to waye laarin awọn onifayawọ atawọn aṣọbode niluu Isẹyin lọsẹ to kọja ni miliọnu kan naira.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo sọrọ naa lasiko abẹwo to ṣe si aafin Ọba Abdul Ganiyu Adekunle Salaudeen ti i ṣe Asẹyin tilu Isẹyin fun ipolongo ibo to n bọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.

Makinde ṣalaye pe “Bi nnkan ṣe le koko lorileede yii lasiko yii wa lara idi ti iru eyi ṣe waye nitori awọn eeyan ni lati jẹun.

“Mo ti ri idile bii marun-un ninu awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ yẹn. Mo gbadura fun wọn pe Ọlọrun yoo duro ti wọn. Mo si ṣeleri pe gbogbo nnkan ta a ba le ṣe lati dena iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju la maa ṣe.

“O wu mi ki awọn eeyan ran awọn ẹbi wọnyi lọwọ. Emi gẹgẹ bii ẹni kan, mo ṣeleri lati fun ẹbi oloogbe kọọkan ni miliọnu kọọkan naira (N1m). Bakan naa ni mo maa yan igbimọ to maa lọọ tu awọn eeyan idile naa ninu lati gbe ibanujẹ kuro lara wọn, ki wọn si bẹrẹ si i gbe igbe aye rere wọn pada gẹgẹ bii tatẹyinwa.”

Nigba to n rọ awọn ara ilu Iṣẹgun lati dibo fun awọn to n dije dupo lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo to n bọ lopin ọsẹ yii, Gomina Makinde sọ pe iyẹn ni yoo jẹ ki iṣẹ idagbasoke ilu ti ijọba oun rawọ le lagbegbe naa, bii oju ọna Ibadan si Isẹyin, tẹsiwaju.

Gomina ṣeleri lati ṣe iru atunṣe ọna to ti Ibadan lọ si Iṣẹyin, ọna to ti Isẹyin lọ siluu Ogbomọṣọ bakan naa titi ọdun 2023.

Bẹẹ lo fi da awọn ara Isẹyin loju pe ẹka Fasiti LAUTECH, tilu Ogbomọṣọ, ti oun gbe lọ siluu naa yoo bẹrẹ iṣẹ ki ọdun 2021 ta a wa yii too pari.

Leave a Reply