Makinde gbe ọpa aṣẹ fun Olubadan tuntun

Wale Ajao, Ibaadan

Pitimu lero pe sibi igbade Olubadan kejilelogoji nilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun. Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, igbakeji aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Atiku Abubakar ati Oloye Bọla Ahmed Tinubu, ẹni ti igbakeji gomina Eko nigba kan, Ọtunba Fẹmi Pedro, ṣoju fun, wa nibi ayẹyẹ to waye ni Gbọngan Mapo, niluu Ibadan naa.

Niṣe ni ero n wọ bii omi, to si ṣoro fun awọn ẹṣọ alaabo lati dari awọn ero ọhun pẹlu bi awọn ẹṣọ naa ti pọ to.

Gbogbo awọn ọna to lọ si Mapo bii Iwo Road, Iyana ṣọọṣi, Bẹẹrẹ, Mọkọla, Dugbẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn ẹṣọ wa lati dari ọkọ.

Lati nnkan bii aago meje aarọ, ki eto naa too bẹrẹ rara lawọn eeyan ti n rọ lọ si Mapo Hall ti eto naa ti waye lati le wo bi ohun gbogbo yoo ṣe lọ. Awọn onilu awọn olorin atawọn apẹsa ko gbẹyin nibẹ. Orin ọlọkan-o-jọkan ni wọn fi n da aọn eeyan laraya.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo gba awọn gomina Ekiti, Ogun atawọn ọba alaye bii Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta, Ọọni Ileefẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi atawọn alejo nla nla bẹẹ lalejo.

Awọn ọmọ bibi ilu Ibadan nile loko ati lẹyin odi pẹlu awọn afẹnifẹre gbogbo ni wọn pesẹ sibi ayẹyẹ naa.

Nigba to n gbe ọpa asẹ fun un, Gomina Ṣeyi Makinde rọ ọba tuntun naa pe ko jẹ baba fun gbogbo araalu lai fi ti ẹni kan ṣe.

Ṣaaju  ọjọ ayẹyẹ igbade yii ni Gomina Ṣeyi Makinde ti fi ọkọ olowo nla meji ta ọba tuntun yii lọrẹ.

Leave a Reply