Ọlawale Ajao, Ibadan
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ni yoo gba awọn lọbalọba, parakoyi oniṣowo, atawọn leekan leekan lagbo oṣelu lalejo nibi ariya ti ajọ Yoruba Agbaye, iyẹn Yoruba World Centre, tẹpẹpẹ siluu Ibadan lati bu ọla fun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba (Ọmọwe) Mahood Lekan Balogun.
Ariya ti wọn fẹẹ ṣe fun Olubadan yii ni yoo waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, ninu gbọngan ile nla kan ti wọn n pe ni John Paul II Building, to wa niwaju UI Bookshop, ninu ọgba Fasiti Ibadan.
Ajọ Yoruba World Centre lo tẹ pẹpẹ ariya nla yii pẹlu atilẹyin ileeṣẹ eto iroyin, aṣa ati irinajo afẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ, ati ileeṣẹ aṣa ati iṣẹ ọna to jẹ ti Ọmọọba Tunde Ọdunlade (Tunde Ọdunlade Gallery). Niṣe ni wọn si mọ-ọn-mọ
fi eto naa si ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, lati le jẹ ko ṣe deede ọgọrun-un ọjọ ti Ọba Lekan Balogun gori itẹ gẹgẹ bii Olubadan tuntun.
Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Sẹnetọ Rashidi Adewọlu Ladọja, to tun jẹ Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, ni alaga ayẹyẹ nla naa.
Gẹgẹ bi Alakooso agba fun Ajọ Yoruba Agbaye, Ọgbẹni Alao Adedayọ, to tun jẹ oludasilẹ iweeroyin ALAROYE, ṣe fidi ẹ mulẹ, “Yatọ si ayajọ ọgọrun-un ọjọ ti Ọba Balogun gori itẹ, a tun fẹẹ lo anfaani ayẹyẹ yii fun iṣọkan ati idagbasoke orileede yii ati lati jawe sobi aṣa ati iṣe Yoruba’’.
Nigba to n fi idunnu ẹ han si eto naa lasiko ti igbimọ Yoruba World Centre ṣabẹwo si i laafin rẹ, Olubadan Lekan Balogun sọ pe “mo nigbagbọ pe ọna ti eto yii yoo gba gbe ogo Yoruba yọ lẹ maa gba ṣe e gẹgẹ bo ṣe jẹ pe agbega ogo iran Yoruba lo jẹ yin logun. Emi naa gẹgẹ bii ẹni to pataki ọrọ iran Yoruba, gbogbo ohun to ba ti ni i ṣe pẹlu agbega iran Yoruba bii iru eyi tẹ ẹ gbe kalẹ yii patapata ni ma a maa fọwọ si”.
Lara awọn ti igbagbọ wa pe Gomina Makinde yoo gba lalejo nibi ayẹyẹ naa ni Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi (Ọja II); Alake Ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ atawọn ori ade mi-in pẹlu awọn lookọ lookọ lawujọ.