Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjimnia Ṣeyi Makinde, ti fọwọ si i pe ki Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Akinloye Ọlakulẹhin, jẹ Olubadan ilẹ Ibadan.
Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa yii, la gbọ pe Gomina Makinde ti fọwọ si orukọ baba naa to jẹ Balogun ilẹ Ibadan lọwọlọwọ lati di Olubadan tuntun, ni ibamu pẹlu ifẹnuko awọn afọbajẹ ilu naa, ṣugbọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, l’Ọgbẹni Sulaiman Ọlanrewaju ti i ṣe Akọweeroyin Makinde too sọ igbesẹ gomina yii di mimọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun (19), oṣu Kẹfa, ọdun 2024 ta a wa yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ ninu atẹjade ọhun, “Ni ibamu pẹlu agbara ta a gbe wọ gomina labẹ ori kọkandinlogin (19), ẹsẹ kejidinlọgbọn (28), ofin ipinlẹ Ọyọ, ọdun 2000, Gomina Makinde fọwọ si orukọ Ọba Ọlakulẹhin gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa, ọdun 2024”.
Tẹ o ba gbagbe, lọkọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, l’Ọba Lekan Balogun, ti í ṣe Olubadan ana waja.
Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lawọn afọbajẹ ilẹ Ibadan ti fa Ọba Ọlakulẹhin kalẹ gẹgẹ bii ọmọ oye Olubadan, ti wọn si ti fi orukọ rẹ ranṣẹ sijọba ipinlẹ Ọyọ, ṣugbọn ti Gomina Makinde ko ti i gbe igbesẹ lori bi baba naa yoo ṣe gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bii Olubadan tuntun, nitori to gba pe ara baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84) naa ko ya.
Eyi lo mu ki gomina gbe igbimọ kan dide lati lọọ wo baba naa nile ẹ to wa laduugbo Alalubọsa, n’Ibadan, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun (17), oṣu Karun-un, ọdun yii, ti wọn sì fidi ẹ mulẹ pe ara rẹ ya.
Ṣugbọn sibẹsibẹ, Makinde ko gba, o si sọ ọ nibi ayẹyẹ oku Olubadan Ọba Balogun to waye lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, pe o digba ti ara baba naa ba ya daadaa ki oun too gba lati jẹ ki baba naa jọba.
Lati ọjọ naa lawọn eeyan loniran-n-ran ati lẹlẹgbẹjẹgbẹ ti n fi aidunnu wọn han si gomina fun ọrọ to sọ naa, wọn ni niṣe lo kan n mọ-ọn-mọ fẹẹ fi ipo ọba la Ọlakulẹhin loju, nitori ko si nnkan to ṣe baba arugbo naa bo ti wu ko mọ.
Eyi to dà bíi bọmbu ti wọn ju lu Gomina Makinde lori ọrọ yii lọrọ ti Ọtun Olubadan tilẹ Ibadan, Agba-Oye Rashidi Adewọlu Ladọja, sọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ojo kẹrindilogun(16), oṣu yii, nibo to ti bu ẹnu atẹ lu igbagbọ gomina nipa ilera ọba tuntun naa.
Ṣugbọn nigba ti igbagbọ Gomina Makinde ti yipada lori ilera Ọba Ọlakulẹhin yii, to si ti gba pe ki baba naa gori itẹ, ọjọ ti yoo kede eto iwuye Olubadan tuntun naa lo ku ti gbogbo aye n reti bayii.