Makinde yan Gani Adams ni aṣoju Amọtẹkun, o gbe mọto ti yoo fi ṣiṣẹ naa fun un

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde, ti yan Iba Gani Adams ti i ṣe Aarẹ-Ọna-Kakanfo ilẹ Yoruba gẹgẹ bii aṣoju ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, bẹẹ lo si fun un ni ọmọ ogun mẹta ati mọto kan ti wọn yoo maa fi kun iṣẹ aabo ṣiṣe.

Ile Iba Gani Adams to wa ni Ọmọle, l’Ekoo, lo ti gbalejo ikọ ti Gomina Makinde fi iṣẹ naa ran, o si ṣeleri pe oun yoo lo ipo tijọba Ọyọ yan oun si naa lati ṣiṣe aabo takuntakun.

Nigba to n ṣapejuwe igbesẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ yii, Aarẹ sọ pe ohun iwuri ni, nitori pataki ni aabo jẹ nibikibi, gbogbo ọna lo yẹ ki ipinlẹ fi wa aabo fawọn eeyan rẹ.

Oloye Adams loun mọ riri ohun ti Makinde ṣe yii, oun si ro pe awọn gomina yooku naa yoo ri i bi awokọṣe. Paapaa lasiko yii ti aabo ti doju delẹ pata ni Naijiria, ti ko si ifọkanbalẹ kan.

O fi kun un pe iṣẹ aabo naa ni iṣẹ akọkọ ti awọn Aarẹ-Ọna-Kakanfo maa n ṣe nilẹ Yoruba, nisinyii ti ipinlẹ Ọyọ si ti ri i ni tiẹ pe ẹtọ ni lati fiṣẹ ran ẹni to too fiṣẹ ogun ran, o loun naa yoo lo ipo oun lati mojuto iṣẹ aabo ti Makinde fun oun ṣe.

Oun yoo ti i lẹyin, ṣugbọn ki i ṣe l’Ọyọọ nikan, kari gbogbo ilẹ yii naa ni gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply