Makinde yọ Jumọkẹ Akinjide kuro lara awọn oludibo abẹle ẹgbẹ PDP

Ọlawale Ajao, Ibadan
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti yọ orukọ Oloye Jumọkẹ Akinjide kuro lara awọn ọmọ ẹgbẹ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP ipinlẹ naa to n lọọ dibo yan ẹni ti yoo dupo aarẹ ilẹ yii lorukọ ẹgbẹ naa nipari oṣu yii.
Jumọkẹ Akinjide, ẹni ti baba ẹ, Oloogbe Richard Akinjide, jẹ minisita feto idajọ lorileede yii nigba aye ẹ, loun funra ẹ jẹ minisita keji feto idagbasoke olu ilu Naijiria, niluu Abuja, lasiko iṣejọba Ọmọwe Goodluck Jonathan.
Ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọyọ, ẹni to fidi iroyin yii mulẹ foniroyin oloyinbo kan n’Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, sọ pe Jumọkẹ Akinjide wa lara awọn ti ireti wa pe wọn yoo lọọ dibo ọhun niluu Abuja nipari oṣu yii tẹlẹ, ṣugbọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Gomina Makinde deede gba orukọ obinrin minisita tẹlẹ naa yọ, to si fi
Oloye Adurodẹkun, to wa lati ijọba ibilẹ Ọna-Ara, rọpo orukọ agba oṣelu obinrin naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹ oṣelu Alaburada ko mọ nipa iṣẹlẹ yii, nitori Gomina Makinde funra rẹ lo da igbesẹ ọhun gbe laaye ara ẹ.
Ohun to n kọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lominu bayii ni bi Jumọkẹ Akinjide ko ṣe ni i binu fi ẹgbẹ naa silẹ, nitori ohun ti gomina ṣe fun un yii.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii lawọn agba ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ọyọ binu fi ẹgbẹ naa silẹ, ti wọn si lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu bii APC ati NNPP.

Lara awọn agba oṣelu to ti ṣe bẹẹ fi ẹgbẹ PDP silẹ ni Alhaji Adebisi Ọlọpọeyan, Alhaja Mulikat Akande to ti figba kan jẹ ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin ijọba apapọ ilẹ yii, Sẹnetọ Kọla Balogun, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja lọwọlọwọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply