Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2022 yii, nijọba ipinlẹ Ọyọ yoo kede ẹni ti yoo jẹ Olubadan tuntun.
Ni ibamu pẹlu ilana ti wọn n gba joye nilẹ Ibadan, Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Agba-ijoye Lekan Balogun, nireti wa pe wọn yoo kede gẹgẹ bii ẹni naa ti yoo gori itẹ ọba n’Ibadan.
Nibi ayẹyẹ ikẹyin ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe fun Olubadan ana, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, lo ti sọrọ naa ni papa iṣere Ọbafẹmi Awolọwọ to wa laduugbo Oke-Ado, n’Ibadan, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun yii.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, l’Ọba Adetunji waja, lẹyin to lo ọdun mẹfa nipo ọba, to si lo ọdun mẹtalelaaadọrun-un (93) laye.
Nigba to n fidunnu ẹ han nipa bi logbologbo ọrọ ija oye to waye lẹyin ipapoda Ọba naa ṣe pari wọọrọ lai da eto oye jijẹ n’Ibadan ru, Gomina Makinde sọ pe ko si ohun to yẹ kawọn ọmọ Ibadan maa ṣe bayii ju ki wọn maa dupẹ lọwọ Ọlọrun lọ.
O ni pipari ti Ladọja atawọn agba ijoye yooku ri ija ọhun pari lọgan yii ni yoo jẹ ki eto tete bẹrẹ lati fi Olubadan mi-in jẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigba ti gbobo ija oye lọbalọba bẹrẹ n’Ibadan, ni papa iṣere Awolọwọ yii naa ni mo ti sọ nigba naa lọhun-un pe tọba lemi o ṣe. Inu mi dun pe Ọlọrun ti gbakoso, a ti pari ẹ bayii.
“Mo ti gba iwe lọwọ igbimọ Olubadan, lagbara Ọlọrun, lọjọ Mọnde, a maa ṣe ikede Olubadan tuntun.
“Oriire mi-in leleyii tun jẹ fun iṣẹṣe ilẹ Ibadan nitori ija yii iba ba ilana taa fi n fọba jẹ, bẹẹ, ko bajẹ ri. A dupẹ pe a tun ti pada si baa ṣe n jọba n’Ibadan.
“Ti ọba ba waja niluu mi-in, ija oye to maa n waye lẹyin rẹ le ma jẹ ki wọn ri ọba jẹ laarin ọdun mẹsan-an, ṣugbọn awa n’Ibadan, lẹyin ogoji ọjọ ti Olubadan kan waja, a ti mọ ẹni to kan lati jẹ ẹ. Idi niyẹn to fi je pe aṣiwaju ni wa.”
Awọn alaṣẹ ijọba, oloṣelu, awọn lọbalọba bii aṣoju Ọọni Ifẹ, aṣoju Alaafin, Ataoja Oṣogbo, Iba ti Kiṣi, Onpetu Ìjẹrù, Asẹyin Iṣẹyin, Onilagbẹdu tilẹ Lagbẹdu, Ọba Amuda Akintoye ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa.
Gbogbo awọn agbaagba ijoye ilẹ Ibadan, titi dori Osi Olubadan ilẹ Ibadan, Sẹnitọ Rashidi Adewọlu Ladọja, pẹlu awọn mọgaji mọgaji ilẹ Ibadan ni wọn peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa.
Diẹ ninu awọn ọtọkulu to wa nibi ayẹyẹ naa ni Ọnarebu Stanley Ọlajide (Odidi Ọmọ), ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Iwọ-Oorun Ariwa ati Guusu Ariwa Ibadan nileegbimọ aṣoju–ṣofin ilẹ yii niluu Abuja; Taofeeq Akeugbagold, Amofin Lọwọ Obiṣẹsan, awọn; aarẹ ẹgbẹ igbimọ agba ilẹ Ibadan, Oloye Oluyẹmisi Adeaga; eekan ọmọ ẹgbẹ OPC ipinlẹ Ọyọ, Oloye Ṣina Akinpẹlu, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba ti agba oniroyin Ibadan nni, Ọgbẹni Wale Rufai, Alhaji Gboyega Lawal, ati irawọ oṣere tiata nni, Saheed Balogun (Walata) dari eto gbogbo nibi ayẹyẹ ọhun. Agba ọjẹ olorin juju nni, Ebenezer Obey ati Taye Currency (Baba Ọnarebu), lo forin da awọn eeyan laraya nibi ariya iṣẹyinde Ọba Adetunji ọhun.