Mama mi sọ pe Gomina Sanwoolu ni baba mi, ti ko ba da wọn loju ka ṣe ayẹwo ẹjẹ

Adewumi Adegoke

Ti nnkan kan ba wa to le mu inu ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọ to ti bimọ mẹta, Emmanuel Sanwoolu dun, kinni naa ni ki Gomina ipinlẹ Eko lọwọlọwọ bayii, Babajide Sanwoolu tẹwọ gba a gẹgẹ bii ọmọ rẹ to ni oun jẹ. O ni iya oun sọ foun pe gomina Eko yii lo bi oun.

Nibi tọrọ yii da a loju, to si ka a lara de, ọmọkunrin naa ti gbe gomina yii lọ sile-ẹjọ pe afi dandan, o gbọdọ gba oun gẹgẹ bii ọmọ rẹ ni, ki oun naa si ni gbogbo ẹtọ to tọ si oun labẹ ofin gẹge bii ọmọ.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni gbagede ile-ẹjo giga Delta State High Court, to wa ni Effurun, nijọba ibilẹ Uvwie, nipinlẹ Delta, lo sọrọ naa.

O ni adugbo Oleri, nijọba ibilẹ Udu, nipinlẹ naa, ni iya oun ti wa, oun nikan lo si bi fun Sanwoolu ko too di pe o lọọ fẹ ọkunrin miiran, to si n ṣabiyamọ nibẹ.

Omọkunrin to ni oun ko niṣẹ gidi lọwọ, abọọṣẹ loun n ṣe lati fi bọ iyawo ati awọn ọmọ mẹta toun bi yii sọ pe o da oun loju tadaa pe Sanwoolu ni baba o, ati pe lati bii ọdun mẹtadinlọgbọn sẹyin loun ko ti ri gomina naa.

O ni iya oun ṣalaye foun pe ileeṣẹ aladaani kan ni Sanwoolu ti n ṣiṣẹ niluu Warri, laarin ọdun 1994 si 1995. O ni lasiko naa lo ṣalaabapade ọmọbinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Grace Moses, lati Abule kan ti wọn n pe ni Oleri, ni Delta, laarin ọdun 1994 si 1995 yii, ti wọn si jọ yan ara wọn lọrẹẹ. Ajọṣepọ ọdun naa lo fi loyun fun Sanwoolu lọdun 1994, ti ọkunrin naa ko si jiyan pe oun kọ ni oun fun obinrin yii loyun.  O ni ko pẹ sigba naa ni Sanwoolu kuro ni Warri, ti Grace ko si ri i mọ titi di asiko yii.

Nitori bi Sanwoolu ṣe kọ lati gba ọmọ yii gẹgẹ bii baba rẹ lo mu ki ọmọkunrin naa gba ile-ẹjọ lọ nipasẹ agbẹjọro rẹ,     John Aikpokpo-Martins. Ninu iwe ipẹjọ ti nọmba rẹ jẹ ECC/148/2022, lo ti beere pe: Ki ile-ẹjọ kede pe Sanwoolu ni baba to bi oun fun Grace Moses, to wa lati Oleri, nipinlẹ Delta.

Ki ile-ẹjọ paṣẹ, ko si kan an nipa, fun Gomina Sanwoolu pe ko gba oun gẹgẹ bii ọmọ, ko si fun oun ni gbogbo ẹtọ ati anfani to tọ si ọmọ to bi ninu ni ibamu pẹlu ofin to ba ba aa mu. Ibaa jẹ ti ibilẹ, ti eyi to n sakoso igbeyawo tabi ti eyi to jẹ ofin ilẹ wa.

Bakan naa lo ni ki ile-ẹjọ fofin de ọkunrin naa lati sọ pe oun ki i ṣe baba olupẹjọ tabi ko kọ ojuṣe rẹ lori rẹ silẹ.

Agbẹjọro Emmanuel ni oun tiẹ ti kọkọ fẹẹ sọ pe ki ile-ẹjọ fagi le ẹjọ naa pẹlu bo ṣẹ jẹ pe gomina ni oun ni aṣe imuniti, leyii to fun un laṣẹ lati ma yọju sile-ẹjọ, eyi ti gomina ko si ṣetan lati gbe sẹgbẹẹ kan ko le waa jẹjọọ yii. O ni ṣugbọn oun ti tun gbe iwe mi-in lọ siwaju kootu pe ki wọn paṣẹ fun gomina pe ko gbe ofin imuniti rẹ to ni sẹgbẹẹ kan lati waa ṣe ayẹwo ẹjẹ.

Agbẹjọro naa ni, ‘Eleyii la n reti pe ki gomina waa ṣe ayewo ẹjẹ to ba mọ pe looootọ, oun kọ loun bi ọmọkunrin naa. Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe ofin imuniti rẹ naa lo lo, to ni ofin ko gba oun laaye lati foju bale-ẹjọ gẹgẹ bii gomina, oun ko si ṣetan lati yi eleyii pada.

‘‘Dipo ti iba fi wa fun ayẹwo ẹjẹ yii, niṣe lo sọ fun ile-ẹjọ pe ki wọn ma gbọ ẹjọ naa mọ rara, ki wọn fawe ẹjọ ọhun ya.

‘‘Lati akoko yii di igba ti ẹjọ naa yoo tun waye ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ẹ jẹ ka maa wo o boya ẹri ọkan rẹ yoo fọwọ tọ ọ lọkan, ti yoo si jade wa lati waa ṣe ayẹwo ẹjẹ pẹlu ọmọkunrin naa. Ko pọn dandan ki awọn oniroyin mọ nipa eleyii, a le ṣe e ni idakọnkọ. Ko sẹni to fẹẹ sẹ e lalariwo pẹlu rẹ tẹlẹ, ṣugbọn oun lo n sa fun ọna kan ṣoṣo ti imọ sayẹnsi la kalẹ lati mọ otitọ to wa nidii ọrọ naa.

‘‘Ko si ohun to le nibẹ rara, ti abajade ayẹwo ẹjẹ ba sọ pe ki i ṣe baba Emmanuel, onikaluku yoo maa lọ sile rẹ. Ṣugbọn ti ayẹwo ba fi han pe loootọ oun lo bi Emmanuel, inu ọmọkunrin naa yoo le dun pe oun mọ orisun ibi ti oun ti ṣan wa. Nipa bayii ni yoo fi le ni anfaani lati le lọ sọdọ awọn mọlẹbi Sanwoolu, ko si sọ pẹlu igboya pe ara wọn ni oun. Bẹẹ lawọn ẹbi naa yoo ri i gẹgẹ bii ọkan ninu wọn.’’

Ọkunrin agbẹjọro yii fi kun un pe ipenija to wa ninu ọrọ yii ni pe bi ko ba gba lati ṣe ayẹwo ẹjẹ naa, a jẹpe awọn yoo tun duro fun bii ọdun mẹrin si marun-un ti yoo fi pari ijọba rẹ gẹgẹ bii gomina, ti ko si ni i ni ofin imuniti kankan mọ, ṣugbọn ko sẹni to mọ ohun to le ṣẹlẹ ki ọdun marun-un yii too pe gẹgẹ bi agbẹjọro naa ṣe sọ.

Leave a Reply