Maradona, ogbontarigi agbabọọlu ilẹ Argentina, ti ku o!

Faith Adebọla, Eko

Gbogbo awọn ololufẹ ere bọọlu ni wọn ti n daro ogbontarigi agbabọọlu ọmọ orileede Argentina nni, Diego Armando Maradona to jade laye lẹni ọgọta ọdun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọsan ọjọ Wesidee lọkunrin elege ara naa mi imi ikẹyin lọsibitu kan niluu rẹ, aisan ọkan ni wọn lo pa a.

Titi dasiko to ku yii, ọkunrin naa ni akọni-mọ-ọn-gba fun ẹgbẹ agbabọọlu Argentine Primera División Club, lorileede Argentina.

Ọpọ awọn ololufẹ bọọlu lo maa ranti ipa ribiribi tọkunrin naa ko lasiko idije fun ife-ẹyẹ agbaye to ṣaaju awọn agbabọọlu lati orileede rẹ, ti wọn si gba ife-ẹyẹ naa lọdun 1994.

Leave a Reply