Marundinlaaadọrun ninu awọn ẹlẹwọn to sa lọ ni Imo ti pada sibẹ funra wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ bayii ni pe marundinlaaadọrun ninu awọn ẹlẹwọn ti wọn sa lọ nigba tawọn agbebọn kan tu wọn silẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti pada sọgba ẹwọn naa funra wọn.

Ẹlẹwọn to din diẹ lẹgbẹrun meji (1, 884) lo sa lọ lọgba ẹwọn to wa ni Owerri, nipinlẹ Imo, naa laaarọ kutu ọjọ Mọnde ọhun, nigba tawọn agbebọn kan ya bo ibẹ, ti wọn si ṣilẹkun ẹwọn silẹ pe ki kaluku wọn maa sa lọ.

Ṣugbọn nigba to di ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, awọn mẹtadinlọgọta (57) funra wọn pada wa sọgba ẹwọn ninu awọn ẹlẹwọn yii, gẹgẹ bi alukoro ọgba ẹwọn naa ṣe sọ.

Nigba ti yoo fi di irọlẹ Ọjọruu ti i ṣe Wẹsidee, ọjọ keje, oṣu kẹrin yii, awọn ẹlẹwọn to funra wọn pada wa ti di marundinlaaadọrun gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

Kinni kan to wa ninu ipada wa awọn ẹlewọn naa ni pe awọn ti wọn dajọ iku fun ko pada wa, bẹẹ lawọn ti wọn fun lẹwọn gbere naa ko si ninu awọn to waa fa ara wọn kalẹ funjọba lẹẹkeji yii.

Ṣe lọjọ Mọnde ti awọn ẹlẹwọn naa gba ominira ojiji yii lawọn agbebọn naa tun kọ lu olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo, ti wọn ba ọpọlọpọ mọto awọn ọlọpaa naa jẹ, ti wọn tun yinbọn fun ọlọpaa kan lejika.

Oriṣiiriṣii irinṣẹ ijagun lawọn eeyan naa ko wọ teṣan ọhun, ti wọn ṣina bolẹ, koda, ile agbara awọn ọlọpaa naa ni wọn fẹẹ wọ ba a ṣe gbọ, bi ko ba jẹ pe awọn agbofinro naa ko faaye ẹ silẹ ni.

Ẹgbẹ awọn Ibo ti wọn n pe ni IPOB, iyẹn ‘Proscribed Indigenous Peope of Biafra’ ni ọga ọlọpaa to ṣẹṣẹ kuro nipo, Muhammed Adamu, di iṣẹlẹ ọhun ru. O ni awọn ni wọn gbebọn wọ kọmandi, ti wọn tun lọọ ṣi awọn ẹlẹwọn silẹ lọgba ẹwọn ijọba.

Leave a Reply