Mary sa pamọ l’Ekiti, lo ba tẹ atẹjiṣẹ sawọn obi ẹ pe wọn ji oun gbe ni  

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ ọmọdebinrin ti ko ti i to ogun ọdun, Mary Idris, lori ẹsun pe o ji ara ẹ gbe lati gbowo lọwọ awọn obi ẹ.

Mary lo ko awọn obi ẹ sinu wahala lọjọ kẹsan-an, oṣu yii, pẹlu bo ṣe deede poora, lọjọ keji niya ẹ si lọọ fọrọ to awọn ọlọpaa leti pe ọmọ oun ti sọnu. ugbọn ko pẹ sigba naa ti aburo afurasi naa fi gba atẹjiṣẹ kan pe ki wọn san owo ti wọn yoo fi gba a silẹ.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, lọgan ni wọn bẹrẹ iṣẹ, wọn si tọpasẹ foonu ọhun de ilu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti mu Mary ati ọrẹkunrin ẹ, Victor Oluwaṣe.

Ni bayii, awọn ọlọpaa ti ni yoo foju bale-ẹjọ lori iwa ọdaju to hu.

Leave a Reply