Faith Adebọla
Alaaji Biliaminu Adisa Akinọla, Adele ọba ilu Oṣodi ti sọ pe ọrọ ọba jijẹ niluu Oṣodi, nipinlẹ Eko, fun Alaga ẹgbẹ awọn onimọto NURTW, Alaaji Musiliu Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, da bii ọrọ ẹran aja ti ko le kan lemọọmu lae ni.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu iweeroyin Tribune lọjọ Aiku, Sannde, to lọ yii, Akinọla ni oun ṣi n gbọ ahesọ ọrọ naa ni, oun ko si ro pe ootọ kan wa nibẹ, nitori MC Oluọmọ funra ẹ mọ pe oun ki i ṣe ọmọ bibi ilu Oṣodi.
“Ẹ jẹ ki n la a mọlẹ fun yin pe ti Musiliu Akinsanya (MC Oluọmọ) ba loun fẹẹ jọba l’Oṣodi, adabọwọ ara ẹ niyẹn, ko sẹni to maa ba a fọwọ si i, ko si le jọba ibẹ.
“Ohun to foju han kedere ni pe idile Akinsanya ko wa lati Oṣodi, wọn ki i ṣọmọ Oṣodi, wọn o si si lara awọn idile ọlọba Oṣodi. Ayalegbe ni wọn, tẹnanti wa ni wọn. Mo gbọ ti wọn lo n pitan pe oun wa latilẹ Awori kan nibi kan, emi o mọ ilẹ Awori to n tọka si o.
“Bi wọn ba fi le faaye gba a pe ko jọba Oṣodi, wọn fẹẹ wọ ipo ọba alaye Yoruba nilẹ yẹn. Ori apere ki i ṣe ibi teeyan kan n dide lọjọ kan pe oun maa fowo ra, irọ ni. Awọn ilana ati aṣa pẹlu alakalẹ wa fun ọba jijẹ.
O ru mi loju nigba ti mo gbọ, mo si mọ pe ijọba ipinlẹ Eko ko ni i da a laṣa lati fipa gbe Musiliu Akinsanya le awọn eeyan Oṣodi lori, tori ki i ṣe ọmọọba Oṣodi, idile wọn ko wa lati Oṣodi.
Mo ti wa itan, mo ti tọpasẹ wọn, ko si apa ibikan ti Akinsanya fi ba Oṣodi tan, bẹẹ ni ipo ọba ko tiẹ kan wọn rara.”
Bẹẹ ni Adele Ọba Ọṣodi sọ.