MC Oluọmọ le jọba Oṣodi, o kunju oṣuwọn daadaa -Almaroof

Faith Adebọla, Eko

Ọmọọba AbdulWasiu Almaroof, ti i ṣe Akọwe fun idile ọlọba Kupoluyi ti kede pe Alaaji Musiliu Akinsanya tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, kunju oṣuwọn daadaa, o si lẹtọọ lati jọba ilu Oṣodi, nipinlẹ Eko.

Nibi ipade pataki kan to waye pẹlu awọn mọlẹbi idile Kupoluyi, eyi ti wọn ṣe lagboole wọn l’Oṣodi, lọjọ Tusidee, ọjọ ki-in-ni, oṣu keji yii, lọkunrin naa ti ṣalaye ọrọ ọhun, lorukọ gbogbo mọlẹbi wọn.

Ṣe wọn ni bi ọmọde o ba itan, yoo ba arọba, Ọmọọba Almaroof pitan pe iya agba to bi iya Musiliu Akinsanya, Alaaja Shadia Almaroof lorukọ rẹ, ọkan lara mọlẹbi idile ọlọba Oṣodi si ni.

“Lati idile to n jọba ni Musiliu Akinsanya (MC Oluọmọ) ti wa, idile Kupoluyi ni, ko si ruju rara. Awa mọlẹbi la fori kori, a si ṣepade lati fa a kalẹ gẹgẹ bii ọmo oye idile wa fun ipo ọba Oṣodi.

“A reti pe kawọn idile ọlọba yooku to fẹẹ jọba Oṣodi fa ọmooye wọn kalẹ, ki awọn afọbajẹ si ṣiṣẹ wọn lati fa ẹni ti yoo de ade naa jade.

“Latilẹwa, baalẹ mọkanla lo wa l’Oṣodi, ṣugbọn meji pere ninu wọn nijọba Eko fọwọ si, awọn meji ọhun ni ti idile Ajenifuja ati Kupoluyi. Eyi fihan pe idile Kupoluyi lẹtọọ sipo oye ati akoso niluu Oṣodi, o si wa lakọọlẹ ijọba.

“Bakan naa ni idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa nigba kan ti fidi ẹ mulẹ pe idile Arọta Ologun naa wa lara awọn to lẹtọọ sipo ọba Oṣodi.

“Baba to bi mi, Alagba Salaudeen Almaroof Ewa, ni afọbajẹ akọkọ l’Oṣodi, lati idile ọlọba Kupoluyi naa ni wọn si ti wa.

“Gbogbo eyi fihan pe idile wa lẹtọọ lati jọba l’Oṣodi, idile wa si ni Musiliu Akinsanya, ọmọ bibi idile Kupoluyi ni. Idi igi mẹtala ni mọlẹbi Alagba Salaudeen Almaroof ta a mọ si Arọta Ologun pin si, ọkan ninu wọn si Alaaja Ṣadia Almaroof to bi baba MC Oluọmọ,” bẹẹ ni Ọmọọba Almaroof ṣalaye.

Amọ ṣa, ọrọ yii tako atẹjade kan ti wọn ni Alaaji Maroof-deen Oshodi, ti i ṣe alaga mọlẹbi Oṣodi-Tapa fi lede lọsẹ meji sẹyin lori ọrọ yii, o sọ ninu atẹjade naa pe MC Oluọmọ ko lẹtọọ si ipo ọba Oṣodi tori ki i ṣe ọmọọba, ko si wa lati idile ọlọba rara, tori ki i ṣe ara mọlẹbi awọn, o sọ pe kijọba kilọ fun un, tori ayọjuran lo fẹẹ ṣe, awọn o si ni i gba a laye.

Titi dasiko yii, MC Oluọmọ ko ti i fesi lori awuyewuye yii.

Leave a Reply