Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ meji yooku ninu awọn ọmọde ole to n da awọn eeyan lọna ni marosẹ Eko s’Ibadan, Yinusa Isah ati Ibrahim Muhammed, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.
Awọn ọmọ naa ti wọn ṣẹṣẹ bọ sọwọ bayii ni wọn sa lọ lasiko tọwọ ba mẹta ninu wọn nibi ti wọn ti n dana lagbegbe Alapako.
Bi wọn ṣe sa lọ lọjọ naa, ipinlẹ Kogi ni wọn mori le. Iwadii awọn ọlọpaa teṣan Owode-Ẹgba to ti n ba ọrọ wọn bọ ti ko duro ni wọn fi gburoo wọn si ipinlẹ Kogi.
Awọn mẹta ti wọn ti kọkọ mu lo tu aṣiri awọn meji yooku yii, ti wọn jẹ ko di mimọ pe Kogi ni wọn sa lọ.
Ada mẹta ati igi kan ti wọn gbẹ bii ibọn ti wọn si fi rọba we ara rẹ lawọn ọlọpaa ba lọwọ awọn ọmọ ole tọwọ ṣẹṣẹ ba yii.
Owo to le ni idaji miliọnu (545,000) ni wọn gba lọwọ obinrin ti wọn da lọna l’Alapako lọjọ kẹtadinlogun oṣu yii, bẹẹ ni wọn gba foonu rẹ kan ti i ṣe Itel lọwọ ẹ.
Ni bayii, Kọmiṣanna ọlọpaa tuntun nipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun, ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa bẹrẹ si i ṣọdẹ loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan yii, lati koju awọn oniṣẹ ibi ti wọn n sa pamọ sibẹ.
Bẹẹ lo ni lojoojumọ lawọn ọlọpaa gbọdọ maa wa loju ọna naa, ko gbọdọ figba kan wa lai si ọlọpaa nitosi