Mẹkaniiki fẹṣẹ yọ eyin kọsitọma ẹ l’Agege

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Micheal Adeniyi, ti n kawọ pọnyin rojọ ni kootu Majisreeti to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, latari bi wọn ṣe lọkunrin naa lu kọsitọma ẹ, Adebayọ Salau, lalubami, o tun da ikuuku bo o titi teyin ẹ fi fo yọ.

Nigba tẹjọ ọhun waye l’Ọjọbọ, Wẹsidee yii, Agbefọba, ASP Raji Akeem, ṣalaye pe iṣẹ mẹkaniiki ni afurasi ọdaran yii n ṣe, ọkada ati kẹkẹ Maruwa lo maa n ba awọn eeyan tunṣe ni ṣọọbu ẹ to wa l’Opopona Oyemẹkun, l’Agege, Agege ọhun si loun naa n gbe.

Kẹkẹ Maruwa ni wọn ni Salau n gun ni tiẹ, o n fi kẹkẹ naa kero l’Agege ni, kẹkẹ yii lo dẹnu kọlẹ lọjọ kẹrin, oṣu ki-in-ni, ọdun yii, to fi gbe e lọ si ṣọọbu Micheal. Micheal ni ẹgbẹrun meje loun maa gba fowo iṣẹ atawọn paati (parts) toun maa ra lati ṣe e, wọn si jọ ṣadehun.

Wọn ni Salau tọwọ bapo, o sanwo ọhun fun Micheal, iyẹn si ṣeleri fun un pe ko pada waa gba a l’Ọjọruu, Wẹsidee, to to tẹle e.

Ṣugbọn nigba to di ọjọ kẹta ti wọn fadehun si, naa ko ti i kuro lojukan to wa, wọn ni Micheal o de’di ẹ debii pe o maa tun un ṣe, eyi si bi kọsitọma ẹ ninu gidi, lọrọ ba di awuyewuye laarin wọn.

Awuyewuye naa lo pada dija, ti wọn fi yọwọ ẹṣẹ sira wọn, afi bi wọn ṣe ni ẹṣẹ Micheal ṣe kongẹ ẹnu Salau, ẹṣẹ naa si ka a leyin kan sọnu, gbogbo oju ati ete ẹ naa si wu kudugbukudugbu, lọrọ ba di tọlọpaa.

Wọn ni lafurasi ọdaran naa kọkọ sa lọ, wọn o ri i nile ati ṣọọbu ẹ fọsẹ diẹ, ṣugbọn o pada yọju, awọn agbofinro si fi i sahaamọ titi ti wọn fi pari iṣẹ iwadii, to fi waa dero kootu.

Lara ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ yii ni pe o huwa to le da alaafia ilu ru, o tun ṣakọlu si ọmọlakeji ẹ debi to fi ṣepalara fun un, wọn tun ni niṣe lo fẹtan gba owo lọwọ olujẹjọ. Amọ nigba ti ẹjọ kan Micheal, o loun ko jẹbi.

Adajọ faaye beeli ẹgbẹrun lọna aadọta naira (#50,000) ati ẹlẹrii kan to ni dukia to jọju silẹ fun un. Bi ko ba si kaju beeli, o ni kawọn ọlọpaa ṣi da a pada sahaamọ wọn titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹta, tigbẹẹjọ yoo maa tẹsiwaju.

 

 

 

Leave a Reply