Mẹmunat lọkọ oun ti lahun ju, lo ba ran ajinigbe si i n’Ifọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 Mẹmunat Salaudeen lobinrin to bori dẹdẹ laarin awọn ọkunrin yii n jẹ, ṣugbọn ori to n bo ko ni ko ma ran awọn gende mẹta yii; Ọlayinka Lawal, Asungba Nura ati Usman Oluwatoyin, si ọkọ ẹ pe ki wọn ji i gbe koun le rowo gba lọwọ ẹ, nitori o ni ọkọ oun naa ni ahun ju ijapa lọ.

Iṣẹ ijinigbe ọhun lawọn mẹta naa fẹẹ lọọ ṣe n’Ifọ, nipinlẹ Ogun, tawọn ọlọpaa fi mu wọn pẹlu ada ati okun lọwọ ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii.

Gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ naa ṣọwọ ṣe ṣalaye ṣe sọ, o ni oju ọna Papa/Itori lawọn ikọ ọlọpaa to n ṣọ oju ọna naa ti ri awọn gende mẹta yii lori ọkada, oju wọn ko si jọ ti ọmọluabi, irisi wọn mu ifura dani.

Eyi lo ni o jẹ kawọn ọlọpaa naa da wọn duro, ti wọn yẹ ara wọn wo. Nibi ti wọn ti n yẹ wọn wo ni wọn ti ba okun nla kan to jẹ tuntun lara wọn, pẹlu ada, n lawọn ọlọpaa ba fi kun iwadii wọn lẹnu awọn afurasi naa.

Awọn mẹtẹẹta ko sọ nnkan kan naa, kaluku n pa irọ oriṣiiriṣii nipa ibi ti wọn n lọ ni, ṣugbọn nigba tawọn agbofinro naa ko yee da wọn laamu, wọn jẹwọ pe obinrin kan, Mẹmunat Salaudeen, to n ṣiṣẹ nọọsi laduugbo awọn ni Balogun tuntun, Gas line, Ifọ, lo ran awọn niṣẹ.

Awọn afurasi naa jẹwọ pe Mẹmunat lo fun awọn lẹgbẹrun mẹjọ naira, to ni kawọn fi ra ada ati okun to ba lagbara daadaa to ṣee so eeyan mọlẹ.

Wọn ni iyaale ile naa sọ pe ọkọ oun, toun yoo tan waa ba awọn nibi kan lawọn ni lati ji gbe, bawọn ba si ti ji i gbe tan, kawọn fi okun naa so o mọlẹ bawọn ajinigbe tooto ṣe maa n ṣe, kawọn si waa maa beere owo nla fun itusilẹ rẹ, ko ju bẹẹ lọ.

Wọn ni Mẹmuna sọ pe ọna kan ṣoṣo toun le fi rowo gba lọwọ ọkọ oun ree, afi ki wọn ji i gbe dandan.

Nigba ti aṣiri waa tu ṣa, awọn ọlọpaa lọọ mu Mẹmunat naa, bo si ti ri awọn ọmọ to ran niṣẹ loun naa ti mọ pe awo ti ya.

Ẹsẹkẹsẹ lo jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun loun ran awọn mẹta naa niṣẹ loootọ. O ni ọkọ oun lahun ju, ki i foun lowo, bẹẹ owo wa lọwọ ẹ daadaa.

Mẹmuna sọ pe koun le rowo gidi gba lọwọ baale oun loun ṣe ran awọn ọmọ adugbo si i bii ajinigbe, oun ko mọ pe awo yoo ya.

Wọn ti taari gbogbo wọn lọ sẹka to n ri si ijinigbe fun iwadii si i.

Leave a Reply