Mi o fẹ Senabu mọ, igo lo maa n pa mọlẹ ta a ba n ja, bẹẹ lo maa n gbe mi ṣepe-Suraaju

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọgbẹni Surajudeen Sanyaolu lọkọ Senabu Sanyaolu, ọdun meji naa ni wọn ṣi fi ṣọkọ ara wọn ti Suraju fi n beere ikọsilẹ bayii. O ni Senabu ko mọ ju ko maa pago mọlẹ lati fi gun oun lọ bawọn ba n ja, ko si mọ bi wọn ṣe n ṣadua fọkọ, afepe. Fun idi eyi, ọkunrin naa loun ko fẹyawo mọ o.

Kootu ti wọn ti n gbọ ẹjọ tọkọ-taya l’Ake, niluu Abẹokuta, ni Suraju gbe iyawo rẹ yii lọ. O ṣalaye pe ọmọ meji lawọn bi, ṣugbọn ko si ayọ ninu igbeyawo awọn, afi ija, afi iregbe ojoojumọ latẹnu iyawo oun.

Ohun to ba ọrọ naa jẹ ni ti igo to ni Senabu maa n pa mọlẹ ti yoo fẹẹ fi gun oun.

Ija naa ki i ṣe ẹẹkankan, o ni loorekoore lawọn maa n ja, oun si ti fi ẹjọ rẹ sun iya rẹ atawọn famili rẹ yooku titi, ṣugbọn ko sẹni ti iyawo oun gbọrọ si lẹnu ninu wọn, bẹẹ ni ija n tẹsiwaju.

Ọgbẹni Sanyaolu sọ pe lojiji ni Senabu ko jade nile oun lọdun 2019, ko tiẹ sọ nnkan kan foun to fi lọ. O ni ṣugbọn o kan kuro nile oun ni, o ṣi maa n wa si ibiiṣẹ oun lati waa ba oun ja, ti yoo maa pariwo pe oun ki i ṣe ọkunrin gidi, ti yoo maa doju toun loju awọn oṣiṣẹ yooku.

Ki eyi le ma ṣẹlẹ mọ, ki kaluku si le maa lọ nilọ ẹ labẹ ofin lo ni o jẹ koun wa si kootu, ki wọn tu igbeyawo yii ka, oun yoo maa ṣẹtọ fawọn ọmọ oun bo ṣe yẹ, ṣugbọn oun ko fẹ Senabu mọ ṣa.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Senabu sọ pe oun ko deede fi ọkọ oun silẹ. O ni Suraju ni ko to lọkunrin, nitori ki i tọju oun atawọn ọmọ toun bi fun un, ohun to si maa n faja naa niyẹn.

O loun ki i yọgo sọkọ oun, ko le to bẹẹ yẹn rara. Senabu sọ pe nigba toun ri i pe ko nifẹẹ oun mọ rara loun kuro nile fun un.

Aarẹ A.O Abimbọla lo gbọ ẹjọ wọn, o paṣe pe kawọn ọmọ wa lọdọ iya wọn bi wọn ṣe wa, ki baba wọn si maa ṣẹtọ to yẹ lori wọn. Adajọ sọ pe ki wọn pada wa si kootu fun apero abẹle, lẹyin naa lawọn yoo mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ lori ọrọ wọn.

Leave a Reply