Mi o kabaamọ lori ohun ti mo sọ nipa Tinubu – Ali Ndume

Adwale Adeoye

Pẹlu pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ, iyẹn ẹgbẹ APC nileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja gbimọ pọ, ti wọn yọ ọ nipo pataki to wa lori ọrọ to sọ si Aarẹ Tinubu nita gbangba, Sẹnetọ Ali Ndume loun ko kabaamọ rara, paapaa ju lọ bo ṣe jẹ pe ootọ ọrọ loun sọ nipa iṣakoso Tinubu, ti awọn kan si lẹdi apo po lati kọju ija s’oun.

Idaamu Senato Ali Ndume bẹrẹ latọjọ to ti sọrọ ta ko iṣejọba Aarẹ Tinubu lori afẹfẹ pe Tinubu ti ara ẹ mọ ile ijọba, awọn to ba fẹẹ ri nikan lo n ri, ko jẹ ki ọpọ awọn to n ba a ṣejọba ri i. Ko pẹ si asiko naa ni olori ileegbimọ aṣofin agba niluu Abuja kede pe awọn ọmọ ẹgbẹ  APC ti fẹnu ko laarin ara wọn, ti wọn si ti yọ Ali Ndume nipo rẹ. Koda, alaga ẹgbẹ naa,  Alhaji Ganduje, ati akọwe gbogbogboo ẹgbẹ naa gba a nimọran pe ko kọwe fipo silẹ lori ọrọ to sọ nipa Aarẹ Tinubu.

Ṣa o, Sẹnetọ Ali Ndume naa ti sọrọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, niluu Maiduguri, ti i ṣe ilu abinibi rẹ, pe oun ko kabAamọ rara nipa ọrọ toun sọ nipa Aarẹ Tinubu, ati pe oun tiẹ ti n ro o lọkan oun latigba ti wọn ti kede yiyọ nipo ti wọn yọ oun nipo lati tun fipo alaga igbimọ alabẹṣekele kan toun jẹ nileegbimọ naa silẹ bayii.

O ni, ‘‘Ki i kuku ṣe pe mo ja du ipo Chief Whip ti wọn fi mi jẹ naa rara, awọn kan ni wọn ro pe oye naa tọ si mi, mo ti jẹ olori awọn aṣofin agba tẹlẹ. Kekere loye ti wọn lawọn gba lọwọ mi yii jẹ. Mi o bẹbẹ fun un rara’’.

Nipa pe ko o kọwe fipo rẹ sile ninu ẹgbẹ,

Ndume ni, ‘Mi o ki i ṣ’ọmọde ninu ẹgbẹ APC yii rara, mo wa lara awọn aṣofin mejilelogun ti wọn kuro ninu ẹgbẹ PDP, ti wọn lọọ da ẹgbẹ APC silẹ. Ganduje to jẹ alaga ẹgbẹ APC bayii ko ja mọ nnkan kan lasiko naa, igbakeji gomina ipinlẹ rẹ lo jẹ nigba naa, mo si ranti daadaa pe aimọye igba ni Muhammadu Buhari ati Aarẹ Tinubu fi waa bẹ mi pe ki n waa darapọ mọ ẹgbẹ naa.

‘‘Bi mo ba maa kuro lẹgbẹ APC, awọn kọ lo maa sọ fun mi, ma a kọkọ lọọ ba awọn eeyan mi nile na lati bawọn jiroro nipa rẹ. Ju gbogbo rẹ lọ, mi o kabaamọ ọrọ ti mo sọ nipa Aarẹ Tinubu rara.

Leave a Reply