Mi o ku o, mi o si ninu awọn ti ṣọja yinbọn pa ni Lẹkki-Eniọla Badmus

Ọkan pataki ninu awọn oṣere ilẹ, Ẹniọla Badmus,  wa ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn n pe e, ti wọn n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i nipa iroyin pe ọmọbinrin naa ti ku.  Oṣere naa ni oun ko ku o, alaafia ara loun wa, o ni oun ko tiẹ si ni ibi iwọde naa lanaa rara.

Ninu ọrọ kan to gbe sori ikanni instagraamu re l’Ọjọbọ, Wẹsidee, ọsẹ yii lo ti sọ pe oun wa laye, oun si wa laaye, ohunkohun ko ṣe oun.

Lati ana ni awọn eeyan ti n gbe e kiri ori ẹrọ ayelujara pe oṣere naa wa ninu awọn ti wọn yinbọn fun lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, to si ti ku, nigba ti awọn ṣọja ya bo awọn ọdọ naa nibi ti wọn kora pọ jọ si, ti wọn si n yinbọ fun wọn. Ọpọ awọn ọdọ naa lo ku, nigba ti pupọ ninu wọn tun farapa yanna yanna, ti wọn si n gba itọju nileewosan di ba a ṣe n sọ yii

Oṣere naa wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn afẹnifẹre ti wọn ti n pe e lati beere alaafia re. Bẹẹ lo ni ki enikẹni ma sunkun fun oun o, nitori oun ko ku, oun wa laye, oun wa laaye, ṣugbọn inu oun ko dun nitori aburu ti awọn ṣọja ṣe si aọn ọdọ ti wọn n ṣewọde jẹẹjẹẹ wọn.

Leave a Reply