Mi o le da iyawo mi mu ni mo ṣe la ọmọ-odo mọ ọn, mi o mọ pe o maa ku- Christoher

Christopher Chiabata lọkunrin yii n jẹ, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta( 56) ni. Atimọle lo wa bayii, lọdọ awọn ọlọpaa, ni Bayelsa. Ohun to fa a naa ni ti iyawo ẹ to la ọmọ odo mọ nigba ti wọn n ja, tiyẹn si ṣe bẹẹ ṣubu lulẹ, to ku patapata.

Owo lo dija silẹ laarin Christopher ati iyawo ẹ toun jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji(41). Ile wọn to wa ni Onuebum, nijọba ibilẹ Ogbia, nipinlẹ Bayelsa, ni wọn ti jọ n ja lọsẹ to kọja yii lori owo ti iyawo pa lori ere oko ti wọn ta, n lọrọ naa ba di gidigbo, niyawo ba gbe ọkọ ṣanlẹ, lo ba n lu u bii ko ku.

Baba yii funra ẹ lo ṣalaye fawọn akọroyin nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lọjọ kẹsan-an, oṣu kẹta yii, pe apa oun ko ka iyawo oun ri, bo tilẹ jẹ pe ọgbọn ọdun ree toun ti fẹ ẹ, to si ti bimọ marun-un foun.

Christopher sọ pe oloogbe maa n lu oun bii ẹni n lu ọmọde ni, ohun to si maa n fa a naa ni toun ba beere iye to pa lori ere oko tawọn jọ n gbin. Ọkunrin yii sọ pe fun ọdun meji gbako, iyawo oun ko foun ni akanti owo to pa nibi nnkan oko naa, boun ba si beere, ajẹkun iya loun yoo jẹ.

Lọjọ ti wahala waa ṣẹlẹ yii, ọrọ owo naa lo dija. O loun tilẹ ti ni ko kẹru ẹ jade nile oun, ko fẹẹ lọ ni. Bi inu ṣe bi oun niyẹn, lawọn ba bẹrẹ si i ja, ni iyawo ba tun mu oun lu bii iṣe rẹ, loun ba ja ara oun gba, loun gbe ọmọ odo to wa nitosi, boun ṣe la a mọ ọn niyẹn, afi wẹjẹ to ṣubu lulẹ.

Awọn eeyan to wa nitosi lo sare gbe obinrin naa lọ si ọsibitu, ṣugbọn o ti ku, bi wọn ṣe mu ọkọ iyawo niyẹn.

Ọkunrin naa yoo de kootu bawọn ọlọpaa ṣe wi, nibi ti yoo ti gba idajọ to yẹ.

Leave a Reply