Mi o le fi ilu Idọgọ ṣere: Oju ọmọ pọn iya mi, ṣugbọn ibẹ ni Ọlọrun ti da a lohun-Ebenezer Obey

Faith Adebọla

Ọkan pataki ninu awọn ilu mọ-ọn-ka olorin ti ko ṣee fọọ rọ sẹyin ni Rẹmilẹkun Arẹmu Ọlaṣupọ Fabiyi ti gbogbo eeyan mọ si Ebenezer Obey.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni wọn ṣe ifọrọwerọ ori ẹrọ ayelujara fun Baba Miliki gẹgẹ bi wọn ṣe tun maa n pe e, eyi ti ALAROYE naa wa nibe.

Baba yii ṣalaye ajọṣepọ rẹ pẹlu ilu Idọgọ, ati idi ti ko ṣe le fi ilu naa silẹ laelae, bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ilu Abẹokuta ni baba rẹ, ti iya rẹ si wa lati Owu.

Baba naa ni oun ko le gbagbe ilu naa, nitori nibẹ ni Ọlọrun ti gbọ adura iya oun, to mu un kuro nipo agan, to si rọmọ bi lẹyin ogun ọdun ti ko bimọ. Bakan naa lo ni iya oun ti kilọ fun oun pe oun ko gbọdọ gbagbe ilu naa laelae.

Obey ni, ”Mo mọ pe awọn kan o mọ bi ọrọ yii ṣe jẹ gan-an, ẹ kuku jẹ ki n fi anfaani yii ṣalaye ẹ. Baba mi wa lati Keesi, ni ilu Abẹokuta. Ọmọ Ẹgba ni baba mi, ni mo ṣe maa n ki ara mi pe emi ‘ọmọ Lakesin, ọmọ oru laa ṣeka’. Ọmọ Owu, ni ilu Abẹokuta, ni iya mi, ọmọ agboole Kupooye. Ọmọ Olowu Oduru ni.

”Ogun ọdun ni mama fi wa nile ọkọ ti ko rọmọ bi, lawọn mọlẹbi ọkọ wọn igba yẹn ba pe awọn eeyan mama mi, wọn ni pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, boya ki awọn mejeeji (iyẹn mama mi ati ọkọ wọn igba yẹn) ṣi fi ara wọn silẹ, ki kaluku tun dan ẹlomi-in wo, boya Ọlọrun aa gbọ adura wọn. Ọrọ yii o tẹ mama mi lọrun tori wọn fẹran ọkọ wọn, lai ka ti airọmọbi yii si, ṣugbọn wọn gba pẹlu ipinnu tawọn mọlẹbi mejeeji ṣe yii, eyi lo mu mama mi wa si Abẹokuta.

”Sibẹ ninu ikarisọ ni wọn n wa lojoojumọ, ẹgbọn wọn obinrin kan lo waa sọ fun wọn pe ki wọn kọja sọdọ ẹgbọn wọn to wa n’Idọgọ. Ẹgbọn mama mi kan wa ni ilu Idọgọ nigba yẹn. Ilu Abẹsẹ ni wọn ti ṣi lọ si Idọgọ, tori Abẹsẹ yẹn da bii oko wọn ni, nitori owo koko (cocoa) ṣiṣe. Wọn n ṣọgbin koko, ilẹ wọnyẹn si daa fun koko, ni mama mi fi lọ sọdọ ẹgbọn wọn pẹlu ireti pe wọn aa tura ka, wọn o ni i ronu mọ, ko ma fi ironu pa ara ẹ.

”Baba mi, iṣẹ kafinta ni wọn n ṣe, wọn si n ṣiṣẹ oko ni ilu Idọgọ. Iṣẹ kafinta yii ni ọpọ awọn eeyan baba mi n ṣe pẹlu. Ibẹ ni wọn ti pade mama mi. Bii apara ni wọn ni baba mi sọ lede Ẹgba pe ‘emi re maa fẹ aburo yin yii o’, wọn sọ bẹẹ fun awọn ẹgbọn mama mi. Bii ere, bii ere, bo ṣe di pe wọn sun oorun ọmọ niyẹn, loyun ba de, oyun alakọọkọ, wọn fi bi ẹgbọn mi obinrin, tiyẹn ti ṣalaisi bayii. Oyun ẹlẹẹkeji ni wọn fi bi ẹni ti ẹ waa mọ lonii yii si Ebenezer Obey. Gbogbo asiko ti o rọgbọ ti mama mi la kọja yẹn lo mu ki mama mi sọ pe Ebenezer ni orukọ tawọn fẹ ki wọn sọ mi, leyii to tumọ si pe ibi ni Ọlọrun ran mi lọwọ de (emi ti wọn n pe lagan, ti wọn ni mio le bimọ mọ, ibi ti Ọlọrun ba mi ṣee de ree o). Nigba to ku diẹ ki wọn bi mi, wọn lọ si ilu Eko, lo fi jẹ Eko ni ọsibitu ti wọn bi mi si, lẹyin ti mo ti daye, wọn gbe mi pada siluu Idọgọ ni ikoko. Ibẹ si ni mo dagba si, ibẹ ni mo ti ṣe kekere mi, ibẹ la n gbe titi.

”Nigba ti mo ti dagba, ti mama mi naa ti dẹni ogbo, wọn pe mi lọjọ kan, wọn ni ‘Ọlaṣupọ Arẹmu, ma fi Idọgọ silẹ o, ma gbagbe Idọgọ o, Idọgọ ni Ọlọrun ti daṣọ bo ihooho mi o, ibẹ ni Ọlọrun ti gbọ adura mi o’. Bi mama mi ṣe sọ fun mi ki wọn too ku niyẹn.

”Nigba kan ti awọn ọmọ ẹgbọn mama mi wa sile lati Amẹrika, wọn sọ fun mama mi pe ki wọn ba awọn dupẹ lọwọ mi o, ‘Dadi (emi) ra ile kan fawọn ni Amẹrika o’. Mama ni ṣe loootọ, ni wọn ba tun ran mi leti pe, ‘o baa kọ ile ogun (20), o gbọdọ kọ si ilu Idọgọ, tori ibi ti adura ti gba niyẹn.’ Iyẹn lo fi jẹ pe Idọgọ ko ṣee yọ kuro ninu itan igbe aye mi. Mi o le gbagbe Idọgọ, bi mo ṣe n ṣe nnkan si Abẹokuta naa ni mo n ṣe si ilu Idọgọ. ”

Leave a Reply