Mi o le tọrọ aforiji lọwọ ẹnikẹni nitori ọrọ ti mo sọ-Olurẹmi Tinubu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Latari ọrọ to ṣe bii ọrọ laarin Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu to n ṣoju Aarin gbungbun Eko l’Abuja, ati obinrin kan, Arin Ọlọkọ, lotẹẹli Marriot, l’Ekoo, l’Ọjọruu, to kọja yii, Iyawo Aṣiwaju Tinubu loun ko ni aforiji kan toun yoo tọrọ lori ohun ti oun sọ, o ni bo ṣe ri loun ṣe sọ ọ yẹn.

Tẹ o ba gbagbe, ohun to n ja ran-in lori ayelujara ni gbogbo ọsẹ naa ni fidio kan to ṣafihan Sẹnẹtọ Olurẹmi Tinubu ati awọn eeyan kan ti wọn jọ n tahun sira wọn nibi eto kan ti wọn fẹẹ fi ṣagbeyẹwo ofin ilẹ wa ti wọn ṣe lọdun 1999.

Niṣe ni awọn akopa n to wọle lẹnu ọna otẹẹli naa, iyẹn lẹnu ọna iwaju ti wọn ṣi kalẹ fawọn eeyan lati maa gba wọle. Nigba ti Gomina Babajide Sanwo-Olu si de, oun ko gba ẹnu ọna tawọn eeyan n gba naa wọle, ọna ẹyin lo gba, ni eto ba fẹẹ bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ, wọn si tilẹkun abawọle tawọn eeyan n gba tẹlẹ pa.

Eyi lo bi awọn akopa ti wọn wa lori ila lasiko ti wọn tilẹkun naa ninu, awọn eeyan naa bẹrẹ si i sọrọ pe ko yẹ ki wọn ti awọn mọta bẹẹ nitori gomina de.

Ko pẹ sigba naa ni Sẹnetọ Tinubu jade lati ọna ẹyin, o si fẹ kawọn aṣofin kan lati ipinlẹ Ọyọ gba ibẹ wọle. Asiko naa ni obinrin kan ti wọn ko jẹ ko wọle ni tiẹ yari, to ni ojuṣaaju ni wọn n fi eto iwọle naa ṣe, ko si yẹ ko ri bẹẹ.

A gbọ pe bi obinrin naa ṣe n binu ni Iyawo Tinubu pe e pẹlu awọn meji kan pe ki wọn waa wọle, o si beere lọwọ obinrin naa pe ki lo de to n ṣe bii ọmọọta, ki lo de to n pariwo sọrọ bẹẹ.

Ohun ti Sẹnẹtọ Tinubu sọ yii lo di wahala, to jẹ ẹsẹkẹsẹ lawọn eeyan ti yi i mọ ọn lọwọ, wọn ni ki i ṣe pe o pe obinrin naa ni tọọgi, wọn ni dọọgi (Dog) aja, lo pe e laarin ero, ko si yẹ ki ẹni to jẹ eeyan pataki lawujo sọrọ bẹẹ, wọn ni kiyawo Tinubu tọrọ aforiji lọwọ obinrin to pe ni aja naa.

Yatọ sawọn eeyan to wa nibẹ ti wọn gbeja obinrin yii, ọpọ eeyan lori ayelujara to da si i lo bẹrẹ si i sọrọ ti ko daa si Sẹnẹtọ Olurẹmi Tinubu, wọn ni ṣe ẹni to fẹẹ di iyawo aarẹ ni 2023 naa lo n ja nita gbangba yii. Awọn mi-in tilẹ sọ pe obinrin naa fẹran wahala ju, wọn ni ẹnu ki i sin lara rẹ rara.

Ṣugbọn ninu gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii, Sẹnẹtọ to n ṣoju Aarin gbungbun Eko yii loun ko ni aforiji kan toun yoo tọrọ lọwọ ẹnikẹni pẹlu ohun toun sọ naa, o ni nitori ohun ti oun reti ni ki obinrin naa da oun lohun boun ṣe beere pe ki lo de to n ṣe bii ọmọ ita.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, ti wọn gbe Sẹnetọ Olurẹmi Tinubu wa sori eto kan ti wọn n pe ni ‘Your View’ lori tẹlifiṣan TVC, obinrin naa ṣalaye pe oun ko pe obinrin keji yẹn ni aja. O ni nigba to n pariwo laarin ero, toun si n fi ẹsọ ṣalaye fun un pe ko ni suuru, yoo wọle lẹyin gomina, niṣe ni ko gbọ, to ṣaa n pariwo sọrọ, to si n ṣe bii pe ẹnikẹni ko le da a lẹkun rara. Olurẹmi sọ pe idi niyẹn toun fi beere lọwọ ẹ pe ki lo dẹ to n ṣe bii ọmọọta (Why are you acting like a thug)

Iyawo Tinubu lohun toun sọ ree, oun ko pe e laja, ibeere loun beere, oun si ro pe obinrin naa yoo dahun pe oun ki i ṣe tọọgi, oun yoo si waa sọ fun un pe bi ko ba ki i ṣe tọọgi, ko ni suuru, koun yanju ọrọ naa, yoo si pada wọle.

O ni ṣugbọn awọn eeyan lo sọ ọ di nnkan mi-in mọ oun lọwọ, oun ko si ni aforiji kankan lati tọrọ, nitori oun ko sọ ohun ti ko tọ, ohun toun ri loun sọ.

Leave a Reply