Mi o mọ nnkan kan nipa iku Timothy, akẹkọọ Fasiti Ifẹ to sun si otẹẹli mi – Adedoyin

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alaga otẹẹli Hilton Hotel and Resorts to wa niluu Ileefẹ, Dokita Abdulramon Adegoke Adedoyin, ti sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ to di awati lẹyin to sun si otẹẹli naa.

Ninu fọnran kan to n lọ kaakiri ori afẹfẹ ni Adedoyin ti sọ pe oun ti lowo lati nnkan bii ọdun mọkandinlogoji sẹyin, ko si si idi kankan ti oun fi nilo lati paayan tabi ṣe oogun owo gẹgẹ bi awọn kan ṣe n sọ kaakiri.

O ni, “Emi Dokita Abdulramon Adegoke Adedoyin ki i ṣe apaayan tabi ẹni to n gbe eeyan ṣe oogun owo, Ọlọrun Ọba ti fun mi lowo mi latigba ti mo ti wa ni ọmọ ọdun mẹrinlelogun, titi ti mo fi di ọmọ ọdun marunlelọgọta bayii.

“Mi o paayan ri o, Musulumi ododo ni mi, ẹni ti a n pe orukọ rẹ ni Timothy Adegoke gba yara si Hilton Hotel, Ileefẹ, ni Room 305, awọn ọmọ ti wọn gba a wọle si otẹẹli wa ko san owo sinu otẹẹli, ko si si akọsilẹ pe oun gan-an san owo sinu akanti Wema Bank ti a n lo, a ko waa mọ nnkan to ṣẹlẹ ti wọn fi gba a wọle lai jẹ pe o san owo sinu akanti ileeṣẹ, ti wọn si gba a sinu akanti ti ara wọn.

“Igba ti awọn ọlọpaa n wa Timothy Adegoke ni mo too mọ pe nnkan kan ṣẹlẹ nileetura Hilton. Nigba ti wọn si ṣe iwadii, wọn ri oku Timothy nibi ti wọn ju u si, gbogbo awọn ọlọpaa ti wọn wa nibẹ ni wọn wo ẹya-ara rẹ, wọn si ri i pe ẹyọ nnkan kan ko din nibẹ, lati le fidii rẹ mulẹ pe ko si ẹni to ran ẹnikankan lati yọ ẹya-ara rẹ.

“Mo rọ gbogbo eniyan nile, loko, alejo, ara-ile pe ki wọn ni suuru, ki wọn jẹ ki ọlọpaa ṣe iwadii daadaa. Ti ẹ ba wo o daadaa, ẹ maa ri i pe Ileefẹ ni mo ti bẹrẹ gẹgẹ bii ẹni to n ṣe lẹsinni fun awọn ọmọ ninu ile, ki n too da Universal College of Technology silẹ, mo ṣe The Polytechnic, mo ṣe Fasiti.

“N ko kuro niluu Ifẹ ti Ọlọrun Ọba fi da mi lọla, to si fun mi ni owo tutu, ki i ṣe owo-ẹjẹ, ki i ṣe owo buruku, ẹ jọwọ, ki ẹnikẹni ma ṣe ro buruku si mi o. Emi ni Dokita Abdulramon Adegoke Atọbatẹlẹ Adedoyin, Mayẹ ti ilẹ Ifẹ, Mayẹ ti ilẹ Yoruba. Ẹ ṣe o.”

Leave a Reply