Oluyinka Soyemi
Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, ti sọ pe oun ko ni i ṣatilẹyin fun ẹnikẹni to ba fẹẹ dupo aarẹ ilẹ yii lọdun 2023 lati ilẹ Hausa, nitori iha Guusu Naijiria lo tọ si.
Ọkunrin yii ni bo tilẹ jẹ pe ko si ninu ofin ilẹ yii ki wọn maa gbe ipo naa lati iha kan si ekeji, ṣugbọn o wa ninu agbekalẹ APC, o si yẹ ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ ṣatilẹyin fun igbesẹ naa.
O sọ ọ di mimọ pe ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo lo lanfaani lati dupo naa ni 2023, nitori pe Aarẹ Muhammadu Buhari yoo lọ ọdun mẹjọ, o si tọ si awọn eeyan Guusu ilẹ yii kawọn naa lo ọdun mẹjọ.
O waa sọ pe ko si ootọ ninu iroyin tawọn eeyan n gbe kiri pe oun fẹẹ dupo aarẹ nitori Ọlọrun nikan lo n gbe eeyan debẹ.