Mi o ni i fẹyinti nidii oṣelu titi ti ma a fi di aarẹ Naijiria-Tinubu

Ọrẹoluwa Adedeji
Niluu Markurdi, nipinlẹ Benue, ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, oludije funpo aarẹ labẹ ẹgbẹ APC ti sọ fun awọn ọdọ agbegbe naa pe loootọ loun ti dagba o, ti wọn si n reti pe ki oun fẹyinti, ṣugbọn oun ko ni i fẹyinti nidii oṣelu, afi ti oun ba di aarẹ Naijiria.
Gẹgẹ bi iweeroyin Daily Trust ṣe sọ, ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni gomina Eko tẹlẹ naa lọ si Markurdi lati ba awọn aṣoju ti yoo dibo lasiko idibo abẹle wọn to n bọ sọrọ pe ki wọn dibo fun oun, ki oun le di aarẹ ilẹ wa.
Tinubu rọ awọn ọdọ ipinlẹ naa pe ki wọn lọọ gba kaadi idibo wọn. O fi kun un pe oun ati awọn elẹgbẹ oun ti wọn wa nibi ipolongo naa atawọn ti ko si nibẹ wa lẹyin awọn ọdọ naa gbagbaagba.
O ṣeleri pe oun yoo da ireti awọn ọmọ orileede yii pada ti wọn ba dibo yan oun gẹgẹ bii aarẹ ilẹ wa.

Leave a Reply