Mi o ri ti awọn to n sọ pe ki n fipo silẹ ro-Emefiele

Monisọla Saka

Olori banki apapọ ilẹ wa, Ọgbẹni Godwin Emefiele, ti ni oun o ti i mọ ohun to maa ṣẹlẹ si oun nipa ọrọ to n ja ran-in nilẹ lori ipo aarẹ toun fẹẹ du.

Nigba tawọn oniroyin lọọ ba a lẹyin to ba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣepade tan l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun yii l’Abuja, nipa erongba rẹ lori ipo aarẹ to n du ati ipo olori banki apapọ to di. Ọrọ naa jẹ eyi to n ka awọn eniyan orilẹ-ede yii atawọn ilẹ okeere lara, esi ti yoo tẹnu Emefiele jade ni pe ki Buhari jẹ ki ọrọ naa kọ wọn lominu, ko di ijaya fun wọn, o ni, “Ẹ jẹ ki ijaya odi mu wọn. O daa keeyan larun ijaya odi”.
O tẹsiwaju pe pẹlu iha ti awọn eeyan ilẹ yii, ẹgbẹ alatako kan ṣoṣo, iyẹn PDP, atawọn orilẹ-ede agbaye kọ si igbesẹ oun, nitoun o, faaji loun n ṣe, oun ko ri tiwọn ro.
Lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, ni wọn ni ẹgbẹ awọn agbẹ atawọn oniṣowo kan ra fọọmu miliọnu lọna ọgọrun-un Naira fun Emefiele lati dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, leyii to sọ pe oun ko mọ nipa ẹ.
Olori fun banki apapọ ilẹ wa ọhun ti kọkọ gba ile-ẹjọ lọ lati ta ko ofin to rọ mọ aṣẹ ijọba to sọ pe ki awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba kọwe fiṣẹ silẹ ki wọn too le dupo kankan ninu eto idibo orilẹ-ede Naijiria.
Nigba tawọn oniroyin bi i pe ki lo ri sọ si atẹjade lati ọfiisi aarẹ to ni ko kọwe fiṣẹ silẹ, Emefiele dahun pe, “Ko si tuntun, bẹẹ, ni ko si iroyin bayii, ṣugbọn iroyin yoo wa laipẹ. O gbọ mi ye, mo ni ko si iroyin bayii ṣugbọn iroyin yoo wa “.

Ẹgbẹ alatako, PDP, ti sọ pe ki wọn yọ Emefiele niṣẹ, ki wọn mu un, ki wọn si ṣewadii nipa ẹ. Akọwe iroyin ẹgbẹ PDP, Debọ Ologunagba, sọ pe, “Igbimọ apapọ gbogbogboo tun n tẹnu mọ ọn pe ki wọn jẹ ki Olori banki apapọ ilẹ yii, Godwin Emefiele, fiṣẹ silẹ, ki wọn fi panpẹ ọba gbe e, ki wọn si ṣewadii to jinlẹ lori ẹsun iṣowo mọkumọku ninu banki apapọ ilẹ wa, eyi to ṣokunfa ọrọ aje wa to dẹnukọlẹ.

” Banki apapọ ilẹ wa ni wọn n tọju gbogbo awọn ohun eelo ti awọn ajọ eleto idibo INEC n lo lasiko awọn eto idibo ilẹ wa si. Lẹyin to si ti han gedegbe pe ọmọ ẹgbẹ APC ni, a o le fọkanbalẹ gbe gbogbo awọn ohun eelo awọn ajọ INEC si ikawọ Ọgbẹni Emefiele, nitori eyi ni koko pataki fun eto idibo ti ko ni i mu wahala ati magomago lọwọ ”

Leave a Reply