Mi o sọ pe kẹ ẹ dibo fun Buhari ni 2015 o, Jonathan ni mo ni kẹ ẹ le lọ -Ṣoyinka

Faith Adebọla, Eko

Ogbontarigi akọwe-kọ-wura nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti bẹnu atẹ lu awọn ti wọn fẹsun kan an pe o wa lara ẹni to ṣatilẹyin fun iyansipo Aarẹ Muhammadu Buhari lọdun 2015, Ṣoyinka ni ọrọkọrọ lawọn eeyan fẹẹ fi kọ oun lọrun, oun o sọ pe kẹnikan dibo fun Buhari, tori oun gan-an alara o dibo fun un, o ni Aarẹ Jonathan to wa lori aleefa nigba yẹn loun ni kawọn eeyan ma dibo fun.
Ṣoyinka sọrọ yii nibi ipade pẹlu awọn oniroyin to ṣe l’Erekuṣu Eko, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.
O ni eti oun ti kun fun ọpọ ẹsun tawọn eeyan fi n kan oun lori ẹrọ ayelujara, ti wọn n sọ pe imọran oun lawọn tẹle ti awọn fi dibo yan Buhari sipo, iṣakoso Buhari naa ko si ṣe awọn loore, niṣe lawọn n ge ika abamọ jẹ.
“Irọ ni o, awọn ti wọn n sọ pe mo ṣatilẹyin fun iyansipo Buhari, wọn o sọ ootọ. Ohun ti mo sọ nigba yẹn ni pe ẹ ma dibo fun Jonathan.
“Ẹtọ mi labẹ ofin ni lati dibo fun ẹnikẹni to ba wu mi, ti onitọhun ba si ja mi kulẹ, ẹtọ mi ṣi ni lati sọ bẹẹ.
“Ṣugbọn ootọ ibẹ ni pe lasiko tawọn oloṣelu n lọ kaakiri lọdun 2015 yẹn, ko si gomina kan tabi aarẹ ti mo fontẹ lu, mi o si sọ fẹnikẹni lati dibo feyikeyii ninu wọn.
“Gbogbo ẹsun ti wọn fi n kan mi lori ẹrọ ayelujara, awọn onirọ ati ẹlẹtan ẹda kan ti wọn o mọ ju ki wọn maa ta epo saṣọ aala ẹlomi-in lọ lo wa nidii ẹ, ko si yẹ kẹnikan gba wọn gbọ.
“Ohun tawọn eeyan sọ ẹrọ ayelujara da lorileede yii ko daa rara, ko si irọ ti wọn o le hun lori ẹ, ọrọ katikati ati eke ni wọn fọn sori afẹfẹ, ẹ ma gba wọn gbọ.” Ṣoyinka lo pari ọrọ rẹ bẹẹ.

Leave a Reply