Michael Adunọla ti fara han niwaju ile-ẹjọ Majisreeti ilu Ileefẹ lori ẹsun pe o pa iyawo atọmọ rẹ.
Adunọla ni wọn fẹsun kan pe o lẹdi apo pọ pẹlu ọrẹ rẹ kan, Atinukẹ Ọlawọyin, lati ṣiṣẹ ibi naa lọjọ kẹtalelogun, oṣu karun-un, ọdun yii.
Laago mejila ọsan ọjọ naa lawọn mejeeji huwa ọhun, wọn pa Iyawo Micheal, Esther, ati Glory, ọmọ rẹ ti ko ju ọmọ oṣu mẹrinla lọ, sinu ile wọn to wa ni Isalẹ-Agbara, niluu Ileefẹ.
Inspẹkitọ Sunday Ọsanyintuyi ṣalaye ni kootu pe lẹyin ti Micheal ati Atinukẹ pa awọn mejeeji tan ni wọn tun ge ori ati ọwọ wọn mejeeji.
Ọsanyintuyi sọ siwaju pe iwa tawọn olujẹjọ mejeeji hu nijiya labẹ ipin okoolelọọọdunrun o din ẹyọ kan (319) abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Oṣun.
Adajọ Muhibah Ọlatunji sọ pe ẹsun tawọn ọlọpaa fi kan awọn olujẹjọ mejeeji ki i ṣe eyi ti ile-ẹjọ Majisreeti le gbọ.
Nitori naa lo ṣe paṣẹ pe ki agbefọba ṣe ẹda iwe ẹsun naa lọ si ẹka to n gbọ ẹjọ awọn araalu (Director of Public Prosecution) nileeṣẹ to n ri si eto idajọ nipinlẹ Ọṣun.
Titi igba naa, Ọlatunji ni ki wọn lọọ fi awọn mejeeji sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, tigbẹẹjọ yoo tun waye lori ọrọ wọn.