Miliọnu lọna ọgbọn lawọn to ji alaboyun atawọn meji mi-in gbe l’Abẹokuta n beere

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Awọn ajinigbe to ji obinrin oloyun oṣu mẹjọ gbe pẹlu awọn meji mi-in loju ọna Igbo-Ọra-Sokoto, nipinlẹ Ogun, lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti ranṣẹ sawọn ẹbi wọn. Wọn ni miliọnu mẹwaa naira lawọn yoo gba lori ẹnikọọkan kawọn too tu wọn silẹ, apapọ owo naa si jẹ miliọnu lọna ọgbọn naira.

Ibi kan ti wọn n pe ni Karigo lawọn ajinigbe ti wọn ni Fulani ni wọn yii ti ya bo awọn marun-un kan lalẹ ọjọ naa, wọn ri mẹta gbe wọgbo lọ, ninu eyi ti alaboyun kan wa ninu wọn.

Awọn meji ti wọn ri ọna jajabọ lọwọ wọn lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn eeyan leti.

Gẹgẹ bawọn eeyan naa ṣe wi, awọn ti wọn ji gbe yii lọọ ṣabẹwo si ọrẹ wọn kan lagbegbe Rounder, l’Abẹokuta, ni. Nigba ti wọn n bọ ti ọna ko daa ni wọn gbe ọkọ wọn sibi kan ti wọn si n fẹsẹ rin.

Nibi ti wọn ti n rin bọ ni awọn Fulani to lugọ ti dena de wọn lọna, ti wọn gbe obinrin meji ati ọkunrin kan wọgbo lọ.

Ọkọ oloyun ti wọn ji gbe yii wa ninu awọn meji ti ori ko yọ, ọkunrin kan ti wọn n pe ni Baba Sandra lo ṣikẹta awọn obinrin meji tọwọ ba naa. Oṣiṣe ijọba ni ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe yii, ẹni kan si n gba ajọ ninu wọn.

Lati ọjọ Sannde ti wọn ti gbe wọn lọ yii, ọjọ Iṣẹgun lawọn ajinigbe naa too pe famili awọn ti wọn ji gbe, ti wọn si ni miliọnu mẹwaa naira ni owo itusilẹ ẹnikọọkan.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn o ni awọn ti wọn ji gbe naa lọọ gbadura lori oke ninu igbo ni.

Oyeyẹmi sọ pe awọn ọlọpaa ti n kilọ fawọn eeyan tipẹ, pe ki wọn yee sọ ara wọn di ounjẹ ajinigbe pẹlu adura ti wọn n lọọ gba ninu igbo lasiko yii, nigba to jẹ ibuba awọn ajinigbe ninu igbo n ṣe.

Bakan naa lo ni bi mọto eeyan ba bajẹ si agbegbe inu igbo bii eyi, keeyan ma duro sibẹ pe oun n wa iranlọwọ, ki tọhun tete kuro nibẹ ko too di pe awọn oniṣẹ ibi ba a nibẹ ni.

Oyeyẹmi sọ pe kọmandi ọlọpaa ko dakẹ lori ọrọ yii, o ni lati alẹ ọjọ Aiku naa lawọn eeyan oun ti n dọdẹ inu igbo yii, ti wọn n wa awọn to ṣiṣẹ ibi ọhun lati le gba awọn ẹni ti wọn ji gbe gbogbo, ki wọn si mu awọn ajingbe naa ṣinkun.

Leave a Reply