Miliọnu marun-un wa fun ẹnikẹni to ba mọ bi a ṣe le ri awọn ajinigbe mẹrin kan-Ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe eeyan mẹrin lawọn n wa lori ẹsun ijinigbe. Awọn eeyan naa ni wọn ni wọn lọwọ si jiji ọkunrin elepo bẹntiroolu kan, Alaaji Suleiman Akinbami, gbe.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa, Ọgbẹni Tunde Mobayọ lo kede ọrọ yii niluu Ado-Ekiti lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori ẹsun ijinigbe to n waye leralera nipinlẹ naa.

Awọn ọdaran mẹrin ti wọn n wa naa ni Samuel Ebira, Jimọh Dele, Dayọ Igwe ati Johnson Ọkada. Ọga ọlọpaa yii sọ pe ẹnikẹni to ba le ta awọn lolobo lori bi awọn yoo ṣe ri wọn mu yoo gba miliọnu marun-un Naira.

ALAROYE gbọ pe awọn ọdaran ọhun sa lọ lasiko ti awọn agbofinro lọọ ṣe akọlu si wọn nibi ti wọn fara pamọ si ninu igbo nla kan to wa ni aala ipinlẹ Ekiti ati Kwara laipe yii.

Ọkunrin oniṣowo epo bẹntiroolu ọhun lawọn ajinigbe yii ji gbe nirọlẹ ọjọ naa nibi to ti n gba atẹgun, ti wọn si gba miliọnu marun-un Naira lọwọ rẹ.

Bakan naa ni wọn tun ji iyawo Sọfeyọ agba nipinlẹ Ekiti, Arabinrin Funmilọla Osalusi, ninu oṣu kẹta, ọdun yii, ti wọn si gba miliọnu meji lọwọ obinrin to jẹ opo yii.

O ni awọn ọlọpaa ti n sa gbogbo ipa wọn lati ri awọn ajinigbe naa mu, ki wọn le fi oju wina ofin, ati pe ẹnikẹni to ba le fun awọn agbofinro ni aṣiri nipa wọn, awọn ko ni i jẹ ki orukọ ẹni bẹẹ di mimọ fun awọn eeyan awujọ.

Mobayọ ni iroyin ijinigbe to n waye leralera nipinlẹ naa jẹ ohun to buru jai, eyi to ni o ti mu ifasẹyin ba orukọ ipinlẹ naa.

O rọ awọn eeyan ipinlẹ naa pe ki wọn maa ran awọn ọlọpaa lọwọ nipa tita wọn lolobo ni gbogbo igba ti wọn ba kẹfin awọn janduku tabi awọn arufin miiran ni agbegbe wọn.

Leave a Reply