Miliọnu mẹta eeyan forukọ silẹ fun N-Power

Ijọba apapọ ti kede pe awọn to le ni miliọnu mẹta lo ti forukọ silẹ fun eto igbanisiṣẹ ati ironilagbara N-Power, bẹẹ ẹgbẹrun lọna irinwo (400,000) pere niṣẹ wa fun.

Eyi waye lẹyin ọsẹ kan pere ti ijọba ṣi ẹka iforukọsilẹ eto naa lori intanẹẹti, eyi to bẹrẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja.

Igbakeji adari ileeṣẹ to n ri si eto ọmọniyan, Rhoda Iliya, lo kede ọrọ naa lonii, ọjọ Ẹti, Furaidee.

O ni ẹgbẹrun lọna irinwo pere lawọn lanfaani lati fun niṣẹ, laipẹ yii si ni gbogbo eto yoo wa sopin lori abala kẹta eto naa to n lọ lọwọ.

Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ọdun 2016, ni Aarẹ Muhammadu Buhari kede eto N-Power lati ran awọn ọdọ ti ko niṣẹ lọwọ, abala meji lo si ti kọkọ waye tẹlẹ lọdun 2016 ati 2017 ko too di ti asiko yii.

Leave a Reply