Miliọnu mẹwaa naira lawọn to ji eeyan meji gbe lọna Ira si Ọffa n beere fun

Stephen Ajagbe, Ilorin

L’Ọjọruu, Wẹside, ọsẹ yii, lawọn ajinigbe ji Hakeem Ojo pẹlu baba agbalagba kan ti a ko ti i mọ orukọ rẹ loju ọna Ira si Ọffa, ti wọn si n beere fun miliọnu mẹwaa naira owo iyọnda wọn.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa waye lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lasiko tawọn mejeeji n bọ lati irin-ajo ninu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Carmy kan.

Ilu Irẹgba, nipinlẹ Ọyọ, la gbọ pe awọn eeyan naa ti n bọ lọjọ naa, nigba to ku bii kilomita diẹ lati wọ ilu Ira, nijọba ibilẹ Ọyun, lawọn agbebọn kan dabuu wọn.

Bi wọn ṣe ko awọn mejeeji lọ niyẹn, ti wọn si pa ọkọ wọn si ibi tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Akọroyin wa gbọ pe awọn ajinigbe naa lo nọmba foonu ọkan lara awọn ti wọn gbe naa lati fi pe awọn ẹbi lati waa san owo iyọlọfin wọn.

Ọsan ọjọ Wẹside la gbọ pe wọn ti yọnda baba agbalagba naa nitori ọjọ ori rẹ, ṣugbọn ẹni keji ṣi wa lahaamọ wọn.

A gbọ pe awọn ọlọpaa ti gbe igbesẹ lori rẹ, wọn si ti n ṣakitiyan lati doola ẹni to ṣi wa nigbekun awọn ajinigbe naa.

Leave a Reply