Miliọnu mẹwaa Yuro ni Partizan fẹẹ ta Umar Sadiq

Oluyinka Soyemi

Ẹgbẹ agbabọọlu Partizan Belgade, ilẹ Serbia, ti sọ pe miliọnu mẹwa Yuro lawọn fẹẹ ta atamatase ilẹ wa, Umar Sadiq, pẹlu bi agbabọọlu naa ṣe n gbona fẹlifẹli lọwọ.

Lopin ọsẹ to kọja ni kilọọbu naa ṣe ikede yii, iyẹn lẹyin oṣu mẹfa pere ti wọn ra ẹni ọdun mẹtalelogun naa lowo to din diẹ ni milọnu meji Yuro lati AS Roma, ilẹ Italy.

Ni bayii ti awọn kilọọbu bii AC Milan, ilẹ Italy, Valencia, ilẹ Spain, ati Fenerbahce, ilẹ Turkey, ti ṣetan lati ra a, Partizan ni awọn ko le ta a kere ju miliọnu mẹwaa Yuro nitori bẹbẹ to n ṣe lọwọlọwọ ko kere rara.

Nnkan ti yoo tun mu idunaa-dura naa dun ni bi CSKA ati Spartak tawọn mejeeji jọ n figagbaga ni liigi ilẹ Russia ṣe n sare lati ra Umar.

Ki i ṣe pe ogo Umar ti n tan ṣaaju akoko yii, oju ẹ ri nnkan lagbo ere idaraya. Lẹyin to darapọ mọ AS Roma, nnkan ko dun fun un rara, bẹẹ ni ko tiẹ gba bọọlu wọle, eyi to jẹ ki kilọọbu naa ta a si kilọọbu mẹfa ọtọọtọ, Partizan yii ni wọn si ta a fun gbẹyin kawọn yẹn too pinnu lati ra a patapata.

Bo ṣe de Partizan lọdun to kọja ni ogo ẹ gbera, bọọlu mejidinlogun loun nikan si gba wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogoji ni saa yii nikan.

Ni ikọ ọjẹ-wẹwẹ, kilọọbu mẹfa ni Umar ti gba bọọlu ni Naijiria ati Italy, nigba to si gba igbega lo gba bọọlu kaakiri kilọọbu mẹjọ nilẹ Italy, Netherlands ati Scotland, ko too lọ si Serbia.

O ti kopa fun ikọ ‘U23’ ilẹ Naijiria nigba mẹfa, bọọlu mẹrin lo si gba wọle.

Leave a Reply