Miliọnu mọkanla naira lawọn Fulani to ji awọn iyalọja gbe loju ọna Ọwọ n beere fun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Titi di ba a ṣe n kọ iroyin yii ni wọn ṣi n wa iyalọja Isua Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Ila-Oorun Akoko, Oloye Edward Helen, atawọn ọlọja mẹfa mi-in tawọn Fulani agbebọn ji gbe lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.

Ibi ipade awọn iyalọja ti wọn n ṣe loṣooṣu niluu Akurẹ lawọn iyalọja naa ti n bọ ki wọn too bọ sọwọ awọn ajinigbe ọhun laarin oju ọna marosẹ Ọgbẹṣẹ si Uṣo.

Awakọ to gbe wọn nikan lo raaye sa lọ ninu gbogbo wọn, oun naa lo si sare lọ siluu Isua lati lọọ royin ohun toju rẹ ri fawọn eeyan.

Awakọ ọhun to n jẹ Jimi ṣalaye f’ALAROYE pe awọn Fulani bii mẹwaa ni wọn deedee jana mọ ọkọ bọọsi awọn lẹnu lojiji pẹlu ibọn AK47 ti wọn gbe lọwọ, eyi ti wọn n yin leralera lati fi dẹruba awọn eeyan.

Awọn ọkọ akero meji mi-in to rin sasiko ti wọn n sọṣẹ lọwọ lo ni awọn ajinigbe naa tun da duro, ti wọn si fipa ko gbogbo ero to wa ninu wọn wọ inu igbo lọ.

O ni ṣe lawọn ajinigbe naa mọ-ọn-mọ fi oun nikan silẹ lẹyin-o-rẹyin la ti lọọ royin ohun to sẹlẹ fawọn eeyan nile.

A gbọ pe awọn ajinigbe naa ti pe awọn ẹbi Oloye Edward sori aago, tí wọn si n beere fun miliọnu mọkanla naira ki wọn too tu u silẹ.

Iroyin awọn ti wọn ṣẹṣẹ ji gbe naa ni wọn lo ti da ibẹru sọkan awọn eeyan ilu Isua ati gbogbo awọn arinrinajo to n kọja loju ọna marosẹ Akurẹ si Ọwọ.

Ọkan ninu awọn agbaagba ilu Afin Akoko, Alaaji Ibrahim Kilani, ni tọsan-toru lo ku tawọn onisẹẹbi naa fi n ṣiṣẹ lawọn oju ọna marosẹ to wa lagbegbe naa lati igba tawọn ọlọpaa ti jokoo pa si tesan latari rogbodiyan to su yọ lasiko iwọde SARS ti wọn ṣe kọja.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni awọn oṣiṣẹ awọn ti ri awọn mẹwaa gba pada ninu awọn ti wọn ji gbe naa.

O ni igbesẹ si n tẹsiwaju la ti ri awọn yooku tu silẹ ninu igbekun awọn to ji wọn gbe.

Leave a Reply