Mimu Sunday Igboho kọ lo jẹ wa logun bayii, alaafia la fẹ – Kọmiṣanna ọlọpaa Ọyọ

Faith Adebọla

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Abilekọ Ngozi Onadeko ti sọ pe ki i ṣe bawọn ṣe maa mu ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, lo jẹ oun logun, oun o si fẹ ohunkohun ju bi alaafia ṣe maa jọba lagbegbe Igangan ati nipinlẹ Ọyọ lọ.

Aṣaalẹ ọjọ Aiku, Sannde yii, lo sọrọ naa nigba to n dahun ibeere lori eto tẹlifiṣan TVC kan, lori erongba rẹ nipa aṣẹ ti ọga ọlọpaa patapata, IG Mohammed Adamu, pa pe ki wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe Sunday Igboho.

Onadeko ni awọn ti parọwa sawọn ọdọ agbegbe Ibarapa, nibi ti wọn ti le awọn Fulani to n gbe niluu naa danu, ti wọn si dana sun ile ati dukia Seriki wọn, pe ki wọn sinmi agbaja na, ki wọn si fun ijọba laaye lati da sọrọ naa ki alaafia le jọba.

O ni iṣẹ iwadii to lọọrin ti bẹrẹ nipa awọn ẹsun oriṣiiriṣii tawọn ọdọ agbegbe naa fi kan awọn Fulani darandaran, ateyi tawọn Fulani naa fi kan awọn eeyan agbegbe naa pada. O ṣeleri pe oun ko ni i figba kan bọkan ninu lori ọrọ ọhun, ati pe bi alaafia ati ibalẹ ọkan yoo ṣe gbilẹ lo jẹ ijọba logun ju lọ.

Ṣaaju, lọsan-an ọjọ naa ni kọmiṣanna naa ti ṣaaju ikọ ijọba apapọ ati tipinlẹ Ọyọ lati ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ bi wọn ṣe dana sun ile olori awọn Fulani niluu naa lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, lasiko ti Sunday Igboho lọ siluu naa lati mu ileri rẹ ṣẹ pe oun ko fẹẹ ri awọn Fulani darandaran kankan mọ ni gbogbo agbegbe Oke-Ogun pata.

Lasiko abẹwo naa, awọn ọba alaye marun-un lati agbegbe Ibarapa ati nipinlẹ Ọyọ, awọn igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa ati Eria Kọmanda nipinlẹ naa, Seriki awọn Fulani lati ilu Igbo-Ọra, ẹgbẹ awọn ọdọ atawọn eeyan pataki ninu Igangan lo ṣepade pẹlu ikọ kọmiṣanna yii.

Ṣa, Onadeko si n tẹnumọ ọn pe awọn maa wa awọn to tina bọ ile ati dukia olori awọn Fulani n’Igangan yii ri.

Leave a Reply